13 Sì kíyèsí i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ijọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Èmáúsì, tí ó jìnnà sí Jerúsálémù níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀.
14 Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀.
15 Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jésù tìkara rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ.
16 Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.
17 Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kínni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro.
18 Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kíléópà, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sáà ni ìwọ ní Jerúsálémù, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”
19 Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jésù ti Násárẹ́tì, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn,