16 Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.
17 Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kínni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro.
18 Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kíléópà, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sáà ni ìwọ ní Jerúsálémù, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”
19 Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jésù ti Násárẹ́tì, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn,
20 Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélèbú.
21 Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Ísírẹ́lì ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹ́ta tí nǹkan wọ̀nyí ti sẹlẹ̀.
22 Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá dá wa níjì: