3 Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jésù Olúwa.
4 Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n:
5 Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn ańgẹ́lì náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú?
6 Kò sí níhínyìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Gálílì.
7 Pé, ‘A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélèbú, ní ijọ́ kẹ́ta yóò sì jíǹde.’ ”
8 Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
9 Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù.