33 Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn,
34 Èmí wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Símónì!”
35 Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mímọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.
36 Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jésù tìkararẹ̀ dúró láàrin wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Àlààáfíà fún yín.”
37 Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì díjì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan.
38 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí ìròkúrò fi ń sọ nínú ọkàn yín?
39 Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkarami ni! Ẹ dì mí mú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”