36 Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jésù tìkararẹ̀ dúró láàrin wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Àlààáfíà fún yín.”
37 Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì díjì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan.
38 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí ìròkúrò fi ń sọ nínú ọkàn yín?
39 Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkarami ni! Ẹ dì mí mú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”
40 Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n.
41 Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhín yìí?”
42 Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè.