45 Nígbà náà ni ó ṣí wọn níyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.
46 Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: Kí Kírísítì jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ijọ́ kẹ́ta kúrò nínú òkú:
47 Àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀ èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálémù lọ.
48 Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.
49 Sì kíyèsí i, mo rán ìlérí Baba mi sí yín: ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerúsálémù, títí a ó fifi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”
50 Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Bétanì, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn.
51 Ó sì ṣe, bí ó ti ń súre fún wọn, ó yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì gbé e lọ sí ọ̀run.