48 Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.
49 Sì kíyèsí i, mo rán ìlérí Baba mi sí yín: ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerúsálémù, títí a ó fifi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”
50 Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Bétanì, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn.
51 Ó sì ṣe, bí ó ti ń súre fún wọn, ó yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì gbé e lọ sí ọ̀run.
52 Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì padà lọ sí Jerúsálémù pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀:
53 Wọ́n sì wà ní tẹ́ḿpìlì nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run. Àmín.