22 Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
23 Jésù tìkara rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Jósẹ́fù,tí í ṣe ọmọ Élì,
24 Tí í ṣe ọmọ Mátatì,tí í ṣe ọmọ Léfì, tí í ṣe ọmọ Melíkì,tí í ṣe ọmọ Janà, tí í ṣe ọmọ Jóṣẹ́fù,
25 Tí í ṣe ọmọ Matataì, tí í ṣe ọmọ Ámósì,tí í ṣe ọmọ Náúmù, tí í ṣe ọmọ Ésílì,tí í ṣe ọmọ Nágáì,
26 Tí í ṣe ọmọ Máátì,tí í ṣe ọmọ Matatíà, tí í ṣe ọmọ Síméì,tí í ṣe ọmọ Jósẹ́fù, tí í ṣe ọmọ Jódà,
27 Tí í ṣe ọmọ Jóánà, tí í ṣe ọmọ Résà,tí í ṣe ọmọ Sérúbábélì, tí í ṣe ọmọ Sítíélì,tí í ṣe ọmọ Nérì,
28 Tí í ṣe ọmọ Melíkì,tí í ṣe ọmọ Ádì, tí í ṣe ọmọ Kòsámù,tí í ṣe ọmọ Élímadámù, tí í ṣe ọmọ Érì,