32 Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.
33 Wọ́n wí fún un wí pé “àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù a máa gbàwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí ṣùgbọ̀n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.”
34 Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó seé se kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ́lú wọn bí?
35 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí ni wọn yóò gbàwẹ̀.”
36 Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé: “Kò sí ẹni tó lè ya asọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba asọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò ṣe dógba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó.
37 Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá otí wáìnì sínú ògbólógbò awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù awo náà a sí.
38 Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun.