20 Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ èyìn rẹ̀, ó ní:“Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòsì,nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run.
21 Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń panísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yòó.Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ńsọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín.
22 Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kóríra yín,tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín,tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú, nítorí ọmọ ènìyàn.
23 “Kí ẹ̀yin yọ̀ ní ọjọ́ náà, kí ẹ̀yin sì fò sókè fún ayọ̀, nítorí tí ẹ̀yin ti gba ìtùnú yín ná.
24 “Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín.
25 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó,nítorí ebi yóò pa yín,Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí,nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún.
26 Ègbé ni fún yín, nígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní rere,nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn èké wòlíì.