36 Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.
37 “Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dáni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín.
38 Ẹ fifún ni, a ó sì fifún yín; òṣùnwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ̀n fún àyà yín: nítorí òṣùnwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ̀n, òun ni a ó padà fi wọ̀n fún yín.”
39 Ó sì pa òwe kan fún wọn: “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí?
40 Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí ó ba pé, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.
41 “Èéṣe tí ìwọ sì ń wo èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí ìtì igi tí ń bẹ lójú ara rẹ?
42 Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ èérún igi tí ń bẹ lójú rẹ,’ nígbà tí ìwọ tìkararẹ kò kíyèsí ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò.