46 “Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí?
47 Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín;
48 Ó jọ Ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi bì lu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.
49 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì se é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi bì lù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”