1 Nígbà tí ó sì pari gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ létí àwọn ènìyàn, ó wọ Kápánáúmù lọ.
2 Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ.
3 Nígbà tí ó sì gbúròó Jésù, ó rán àwọn àgbààgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá.
4 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún:
5 Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀ èdè wa, ó sì ti kọ́ sínágọ́gù kan fún wa.”
6 Jésù sì ń bá wọn lọ.Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu: nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi:
7 Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá: ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá.