21 Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti àrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú.
22 Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yín rí, tí ẹ̀yín sì gbọ́ fún Jòhánù: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúkún-ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòsì ni à ń wàásù ìyìn rere.
23 Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”
24 Nígbà tí àwọn oníṣẹ Jòhánù padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ síí sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Jòhánù pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Iféfèé tí afẹ́fẹ́ ń mì?
25 Ṣùgbọ́n kínni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba!
26 Ṣùgbọ́n kíni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ!
27 Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé:“ ‘Wò ó, mo rán oníṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ;ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’