32 Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé“ ‘Àwa fọn fèrè fún yín,ẹ̀yin kò jó àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín,ẹ̀yin kò sọkún!’
33 Nítorí Jòhánù Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí-wáìnì; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’
34 Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, Ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn “ẹlẹ́sẹ̀!” ’
35 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo dá a nipa ọgbọ́n tí ó lò.”
36 Farisí kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisí náà lọ ó sì jókòó láti jẹun.
37 Sì kíyèsí i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́sẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jésù jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisí, ó mú ṣágo kekeré alabásítà òróró ìkunra wá,
38 Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.