5 Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀ èdè wa, ó sì ti kọ́ sínágọ́gù kan fún wa.”
6 Jésù sì ń bá wọn lọ.Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu: nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi:
7 Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá: ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá.
8 Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”
9 Nígbà tí Jésù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà á sí i, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.”
10 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ-ọ̀dọ̀ náà tí ń sàìsàn, ara rẹ̀ ti dá
11 Ní ijọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Náínì: àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn.