9 Nígbà tí Jésù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà á sí i, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.”
10 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ-ọ̀dọ̀ náà tí ń sàìsàn, ara rẹ̀ ti dá
11 Ní ijọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Náínì: àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn.
12 Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsí i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
13 Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”
14 Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ àga pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!”
15 Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.