11 Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ìwọ ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
12 Lẹ́sẹ̀kan-náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jésù sí ihà,
13 Ó sì wà níbẹ̀ fún ogójì ọjọ́. A sì fi Í lé Èṣù lọ́wọ́ láti dán an wò. Àwọn ańgẹ́lì sì wá ṣe ìtọ́jú Rẹ̀.
14 Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Hẹ́rọ́dù ti fi Jòhánù sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jésù lọ sí Gálílì, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run.
15 Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dèdè. Ẹ yípadà kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”
16 Ní ọjọ́ kan, bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, Ó rí Ṣímónì àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé Apẹja ni wọ́n.
17 Jésù sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”