19 Bí Ó sì ti rìn ṣíwájú díẹ̀, ní etí òkun, Ó rí Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè nínú ọkọ̀ wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe.
20 Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sébédè baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tẹ̀lé e.
21 Lẹ́yìn náà, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapanámù, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsimi, ó lọ sínú sínágọ́gù, ó sì ń kọ́ni.
22 Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kóni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn.
23 Ní àsìkò náà gan-an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú sínágọ́gù wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé,
24 “Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jésù ti Násárẹ́tì? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”
25 Jésù si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúro lára rẹ̀.”