10 Nígbà náà ni Júdásì Ìsíkáríọtù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá, láti ṣètò bí yóò ti fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.
11 Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì pinnu láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.
12 Ní ọjọ́ kìnínní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèṣè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àṣè ìrékọjá?”
13 Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
14 Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baale náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé: Ní bo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àṣè ìrékọja pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’
15 Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèṣè sílẹ̀ dè wá.”
16 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárin ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jésù tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àṣè ìrékọjá.