26 Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ, àti nítorí tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un.
27 Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀sọ ọ̀kan ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Jòhánù wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Jòhánù lórí nínú túbú.
28 Ó sì gbé orí Jòhánù sí wa nínú àwopọ̀kọ́. Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ.
29 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì lọ tẹ́ ẹ sínú ibojì.
30 Àwọn àpósítélì ko ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni.
31 Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ ti wọ́n sì ń bọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó si wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.”
32 Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́.