13 Níbo ni ọba Hamati, ati ti Aripadi, ati ti Sefafaimu, ati ti Hena, ati ti Ifa wà?”
14 Hesekaya ọba gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ, ó kà á. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé OLUWA, ó tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA.
15 Ó gbadura pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ń gbé láàrin àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun tí ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ìwọ ni o dá ayé ati ọ̀run.
16 Nisinsinyii, bojú wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa; kí o sì gbọ́ bí Senakeribu ti ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ìwọ Ọlọrun alààyè.
17 OLUWA, àwa mọ̀ pé ní òtítọ́ ni ọba Asiria ti pa ọpọlọpọ àwọn orílẹ̀-èdè run, ó sì ti sọ ilẹ̀ wọn di aṣálẹ̀.
18 Ó ti dáná sun àwọn ọlọrun wọn; ṣugbọn wọn kì í ṣe Ọlọrun tòótọ́, ère lásán tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ ni wọ́n, iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ eniyan.
19 Nisinsinyii OLUWA Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbà wá lọ́wọ́ Asiria kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA nìkan ni ỌLỌRUN.”