17 OLUWA, àwa mọ̀ pé ní òtítọ́ ni ọba Asiria ti pa ọpọlọpọ àwọn orílẹ̀-èdè run, ó sì ti sọ ilẹ̀ wọn di aṣálẹ̀.
18 Ó ti dáná sun àwọn ọlọrun wọn; ṣugbọn wọn kì í ṣe Ọlọrun tòótọ́, ère lásán tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ ni wọ́n, iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ eniyan.
19 Nisinsinyii OLUWA Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbà wá lọ́wọ́ Asiria kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA nìkan ni ỌLỌRUN.”
20 Nígbà náà ni Aisaya ọmọ Amosi ranṣẹ sí Hesekaya ọba pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Mo ti gbọ́ adura rẹ nípa Senakeribu, ọba Asiria.
21 Ohun tí OLUWA sọ nípa Senakeribu ni pé,‘Sioni yóo fi ojú tẹmbẹlu rẹ,yóo sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà;Jerusalẹmu yóo fi ọ́ rẹ́rìn-ín.’
22 Ta ni o rò pé ò ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí,tí o sì fi ń ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ò ń kígbe mọ́,tí o sì ń wò ní ìwò ìgbéraga?Èmi Ẹni Mímọ́ Israẹli ni!
23 O rán oníṣẹ́ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,o ní, ‘N óo fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi ṣẹgun àwọn òkè,títí dé òkè tí ó ga jùlọ ní Lẹbanoni;mo gé àwọn igi Kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,ati àwọn igi sipirẹsi rẹ̀ tí ó dára jùlọ,Mo wọ inú igbó rẹ̀ tí ó jìnnà ju lọ,mo sì wọ inú aṣálẹ̀ rẹ̀ tí ó dí jùlọ.