28 Mo ti gbọ́ ìròyìn ibinu rẹ ati ìgbéraga rẹ,n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú, n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ lẹ́nu,n óo sì fà ọ́ pada sí ibi tí o ti wá.”
29 Nígbà náà ni Aisaya sọ fún Hesekaya ọba pé, “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nípa àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ nìyí. Ní ọdún yìí ati ọdún tí ń bọ̀, ẹ óo jẹ àjàrà tí ó lalẹ̀ hù, ṣugbọn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ẹ óo le gbin ohun ọ̀gbìn yín, ẹ óo sì kórè rẹ̀, ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì jẹ èso àjàrà rẹ̀.
30 Yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda. Wọn yóo dàbí irúgbìn tí gbòǹgbò rẹ̀ wọnú ilẹ̀ lọ tí ó sì ń so èso jáde.
31 Àwọn eniyan yóo là ní Jerusalẹmu, àwọn eniyan yóo sì ṣẹ́kù ni Òkè Sioni, nítorí pé ìtara ni OLUWA yóo fi ṣe é.
32 “Ohun tí OLUWA sọ nípa ọba Asiria ni pé, kò ní wọ inú ìlú yìí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà kankan sí i. Kò sí ọmọ ogun kan tí ó ní apata tí yóo wá sí ẹ̀bá ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lè gbìyànjú láti gbógun tì í.
33 Ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóo gbà lọ láìwọ ìlú yìí nítorí èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
34 N óo gbèjà ìlú yìí, n óo sì dáàbò bò ọ́ nítorí ògo mi ati ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi iranṣẹ mi.”