12 Ní àkókò kan náà ni Merodaki Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn ranṣẹ sí Hesekaya nítorí ó gbọ́ pé Hesekaya ń ṣe àìsàn.
13 Hesekaya gba àwọn oníṣẹ́ náà ní àlejò. Ó fi gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀, fadaka, wúrà, turari, òróró iyebíye ati gbogbo ohun ìjà rẹ̀ hàn wọ́n. Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra rẹ̀ ati ní gbogbo ìjọba rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n.
14 Nígbà náà ni wolii Aisaya lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekaya, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin wọnyi ti wá, kí ni wọ́n sì sọ fún ọ?”Hesekaya dáhùn pé, “Ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti wá, láti Babiloni.”
15 Aisaya bá tún bèèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ninu ààfin rẹ?”Ọba dáhùn, ó ní, “Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra tí n kò fi hàn wọ́n.”
16 Nígbà náà ni Aisaya sọ fún ọba pé, “OLUWA ní,
17 ‘Àkókò kan ń bọ̀ tí wọn yóo kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ààfin rẹ lọ sí Babiloni, gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ látẹ̀yìnwá títí di òní ni wọn óo kó lọ, wọn kò ní fi nǹkankan sílẹ̀.
18 Wọn yóo kó ninu àwọn ọmọ rẹ lọ fi ṣe ìwẹ̀fà ní ààfin ọba Babiloni.’ ”