Àwọn Ọba Keji 23:14-20 BM

14 Josaya ọba fọ́ àwọn òpó òkúta túútúú, ó gé àwọn ère oriṣa Aṣera, ó sì kó egungun eniyan sí ibi tí wọ́n ti hú wọn jáde.

15 Josaya wó ilé oriṣa tí Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kọ́ sí Bẹtẹli. Josaya wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà níbẹ̀, ó fọ́ òkúta rẹ̀ túútúú, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì jó ère Aṣera pẹlu.

16 Bí Josaya ti yí ojú pada, ó rí àwọn ibojì kan lórí òkè. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn egungun inú wọn jáde, kí wọ́n sì jó wọn lórí pẹpẹ ìrúbọ náà; ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ pẹpẹ ìrúbọ náà di ìbàjẹ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Ọlọrun ti sọ. Nígbà tí Josaya ọba rí ibojì wolii tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà,

17 ó bèèrè pé, “Ọ̀wọ̀n ibojì ta ni mò ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yìí?”Àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli sì dáhùn pé, “Ibojì wolii tí ó wá láti Juda tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí ò ń ṣe sí pẹpẹ ìrúbọ yìí ni.”

18 Josaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi sílẹ̀ bí ó ti wà, kí wọ́n má ṣe kó egungun rẹ̀.Nítorí náà, wọn kò kó egungun rẹ̀ ati egungun wolii tí ó wá láti Samaria.

19 Ní gbogbo àwọn ìlú Israẹli ni Josaya ti wó àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọba Israẹli kọ́ tí ó bí OLUWA ninu. Bí ó ti ṣe pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Bẹtẹli ni ó ṣe àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà.

20 Ó pa gbogbo àwọn alufaa ibi ìrúbọ lórí pẹpẹ ìrúbọ wọn, ó sì jó egungun eniyan lórí gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà. Lẹ́yìn náà, ó pada sí Jerusalẹmu.