12 Wolii àgbàlagbà náà bá bi wọ́n pé, “Ọ̀nà ibo ni ó gbà lọ?” Wọ́n sì fi ọ̀nà náà hàn án.
13 Ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ òun ní gàárì, wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì. Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn,
14 ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa wolii ará Juda náà. Ó bá a níbi tí ó jókòó sí lábẹ́ igi Oaku kan, ó bi í pé, ṣe òun ni wolii tí ó wá láti Juda? Ọkunrin náà sì dá a lóhùn pé òun ni.
15 Wolii àgbàlagbà yìí bá wí fún un pé, “Bá mi kálọ sílé, kí o lọ jẹun.”
16 Ṣugbọn wolii ará Juda náà dáhùn pé, “N kò gbọdọ̀ bá ọ pada lọ sí ilé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí.
17 Nítorí OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé, n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun; ati pé, ọ̀nà tí mo bá gbà wá síbí, n kò gbọdọ̀ gbà á pada lọ sílé.”
18 Wolii àgbàlagbà, ará Bẹtẹli náà bá purọ́ fún un pé, “Wolii bíi rẹ ni èmi náà. OLUWA ni ó sì pàṣẹ fún angẹli kan tí ó sọ fún mi pé kí n mú ọ lọ sí ilé, kí n sì fún ọ ní oúnjẹ ati omi.”