Àwọn Ọba Kinni 1 BM

Ìgbà Ogbó Dafidi

1 Ní àkókò yìí, Dafidi ọba ti di arúgbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ tí ó nípọn ni wọ́n fi ń bò ó, òtútù a tún máa mú un.

2 Nítorí náà, àwọn iranṣẹ rẹ̀ wí fún un pé, “Kabiyesi, jẹ́ kí á wá ọdọmọbinrin kan fún ọ, tí yóo máa wà pẹlu rẹ, tí yóo sì máa tọ́jú rẹ. Yóo máa sùn tì ọ́ kí ara rẹ lè máa móoru.”

3 Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá ọdọmọbinrin tí ó lẹ́wà gidigidi ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli. Wọ́n rí ọdọmọbinrin arẹwà kan ní ìlú Ṣunemu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abiṣagi, wọ́n sì mú un tọ Dafidi wá.

4 Ọdọmọbinrin náà dára gan-an; ó wà lọ́dọ̀ ọba, ó ń tọ́jú rẹ̀, ṣugbọn ọba kò bá a lòpọ̀ rárá.

Adonija Fẹ́ Fi Ara Rẹ̀ Jọba

5 Adonija, ọmọ tí Hagiti bí fún Dafidi, bẹ̀rẹ̀ sí gbéraga, ó ń wí pé, “Èmi ni n óo jọba.” Ó bá lọ tọ́jú kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati aadọta ọkunrin tí yóo máa sáré níwájú rẹ̀.

6 Adonija yìí ni wọ́n bí tẹ̀lé Absalomu, ó jẹ́ arẹwà ọkunrin; baba rẹ̀ kò sì fi ìgbà kan dojú kọ ọ́ kí ó bá a wí nítorí ohunkohun rí.

7 Adonija lọ jíròrò pẹlu Joabu, ọmọ Seruaya, ati Abiatari alufaa, àwọn mejeeji tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

8 Ṣugbọn Sadoku alufaa, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, ati Natani wolii, ati Ṣimei, Rei, ati àwọn akọni Dafidi kò faramọ́ ohun tí Adonija ṣe, wọn kò sì sí lẹ́yìn rẹ̀.

9 Ní ọjọ́ kan, Adonija fi ọpọlọpọ aguntan, pẹlu akọ mààlúù, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ níbi Àpáta Ejò, lẹ́bàá orísun Enrogeli, ó sì pe àwọn ọmọ ọba yòókù, àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní ilẹ̀ Juda.

10 Ṣugbọn kò pe Natani wolii, tabi Bẹnaya, tabi àwọn akọni ninu àwọn jagunjagun ọba, tabi Solomoni, arakunrin rẹ̀.

Solomoni Jọba

11 Natani bá tọ Batiṣeba ìyá Solomoni lọ, ó bi í pé, “Ṣé o ti gbọ́ pé Adonija ọmọ Hagiti ti fi ara rẹ̀ jọba, Dafidi ọba kò sì mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

12 Wá, jẹ́ kí n gbà ọ́ nímọ̀ràn kan, bí o bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ, ati ẹ̀mí Solomoni, ọmọ rẹ.

13 Tọ Dafidi ọba lọ lẹsẹkẹsẹ, kí o sì bi í pé, ṣebí òun ni ó fi ìbúra ṣe ìlérí fún ọ pé Solomoni ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ̀? Kí ló dé tí Adonija fi di ọba?

14 Bí o bá ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ ni n óo wọlé, n óo sì sọ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”

15 Batiṣeba bá wọlé tọ ọba lọ ninu yàrá rẹ̀. (Ọba ti di arúgbó ní àkókò yìí, Abiṣagi ará Ṣunemu ni ó ń tọ́jú rẹ̀.)

16 Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ọba bá bi í pé, “Kí ni o fẹ́ gbà?”

17 Ó dá ọba lóhùn, ó ní, “Kabiyesi, ìwọ ni o ṣe ìlérí fún èmi iranṣẹbinrin rẹ, tí o sì fi orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ búra pé, Solomoni ọmọ mi ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ.

18 Ṣugbọn Adonija ti fi ara rẹ̀ jọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kabiyesi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

19 Ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Abiatari alufaa, ati Joabu balogun rẹ síbi àsè rẹ̀, ṣugbọn kò pe Solomoni, iranṣẹ rẹ.

20 Ojú rẹ ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń wò báyìí, pé kí o fa ẹni tí o bá fẹ́ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ kalẹ̀ fún wọn.

21 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbàrà tí kabiyesi bá ti kú tán, bí wọ́n ti ń ṣe àwọn arúfin ni wọn yóo ṣe èmi ati Solomoni ọmọ rẹ.”

22 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Natani wolii wọlé.

23 Wọ́n bá sọ fún ọba pé Natani wolii ti dé. Nígbà tí Natani wọlé, ó wólẹ̀ níwájú ọba, ó sì dojúbolẹ̀.

24 Ó wí pé, “Kabiyesi, ṣé o ti kéde pé Adonija ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ ni?

25 Ní òní olónìí yìí, ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Joabu balogun, ati Abiatari, alufaa. Bí mo ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, gbogbo wọn wà níbi tí wọ́n ti ń jẹ, tí wọn ń mu, tí wọn ń pariwo pé, ‘Kí Adonija ọba kí ó pẹ́.’

26 Ṣugbọn kò pe èmi iranṣẹ rẹ sí ibi àsè náà, kò sì pe Sadoku alufaa, tabi Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, tabi Solomoni iranṣẹ rẹ.

27 Ǹjẹ́ kabiyesi ha lè lọ́wọ́ sí irú nǹkan báyìí; kí ó má tilẹ̀ sọ ẹni tí yóo gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀?”

28 Dafidi ọba bá ní kí wọ́n pe Batiṣeba pada wọlé. Ó bá pada wá siwaju ọba.

29 Ọba bá búra fún un pé, “Mo ṣe ìlérí fún ọ ní orúkọ OLUWA Alààyè, tí ó gbà mí ninu gbogbo ìyọnu mi,

30 pé lónìí ni n óo mú ìbúra tí mo búra fún ọ ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣẹ, pé, Solomoni, ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn mi.”

31 Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Kabiyesi, oluwa mi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn.”

32 Ọba bá ranṣẹ pe Sadoku, alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, gbogbo wọ́n sì pésẹ̀ sọ́dọ̀ ọba.

33 Ọba bá pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ mi lẹ́yìn, kí ẹ sì gbé Solomoni gun ìbaaka mi, kí ẹ mú un lọ sí odò Gihoni,

34 kí Sadoku, alufaa ati Natani wolii, fi àmì òróró yàn án ní ọba níbẹ̀, lórí gbogbo Israẹli. Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì hó pé, ‘Kí ẹ̀mí Solomoni, ọba, kí ó gùn!’

35 Lẹ́yìn náà, ẹ óo tẹ̀lé e pada wá síhìn-ín kí ó wá jókòó lórí ìtẹ́ mi; nítorí pé òun ni yóo jọba lẹ́yìn mi. Òun ni mo yàn láti jọba Israẹli ati Juda.”

36 Bẹnaya bá dáhùn pé, “Àṣẹ! Kí OLUWA Ọlọrun rẹ bá wa lọ́wọ́ sí i.

37 Bí OLUWA ti wà pẹlu kabiyesi, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ó wà pẹlu Solomoni, kí ó sì mú kí ìgbà tirẹ̀ tún dára ju ìgbà ti kabiyesi, oluwa mi, Dafidi ọba lọ.”

38 Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya, pẹlu àwọn ará Kereti ati àwọn ará Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, bá gbé Solomoni gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Dafidi ọba, wọ́n sì mú un lọ sí odò Gihoni.

39 Sadoku alufaa, bá mú ìwo tí wọ́n rọ òróró olifi sí, tí ó ti mú láti inú àgọ́ OLUWA jáde, ó sì ta òróró náà sí Solomoni lórí. Wọ́n fọn fèrè, gbogbo wọn sì hó pé, “Kí Solomoni, ọba, kí ó pẹ́.”

40 Gbogbo eniyan bá tẹ̀lé e pada, wọ́n ń fọn fèrè, wọ́n ń hó fún ayọ̀. Ariwo tí wọn ń pa pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì tìtì.

41 Bí Adonija ati gbogbo àwọn tí ó pè sí ibi àsè rẹ̀ ti ń parí àsè, wọ́n gbọ́ ariwo náà. Nígbà tí Joabu gbọ́ fèrè, ó bèèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ gbogbo ariwo tí wọn ń pa ninu ìlú yìí?”

42 Kí ó tó dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufaa, dé. Adonija sọ fún un pé, “Máa wọlé bọ̀; eniyan rere ni ìwọ, ó sì níláti jẹ́ pé ìròyìn rere ni ò ń mú bọ̀.”

43 Jonatani bá dáhùn pé, “Rárá o, kabiyesi ti fi Solomoni jọba!

44 Ó sì ti rán Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba pé kí wọ́n tẹ̀lé Solomoni, wọ́n sì ti gbé e gun orí ìbaaka ọba.

45 Sadoku alufaa ati Natani wolii sì ti fi àmì òróró yàn án ní ọba ní odò Gihoni. Lẹ́yìn náà, wọ́n ti pada lọ sí ààrin ìlú, wọ́n sì ń hó fún ayọ̀. Ariwo sì ti gba gbogbo ìlú. Ìdí rẹ̀ ni ẹ fi ń gbọ́ ariwo.

46 Solomoni ti gúnwà lórí ìtẹ́ ọba.

47 Kí ló tún kù! Gbogbo àwọn iranṣẹ ọba ni wọ́n ti lọ kí Dafidi ọba, pé, ‘Kí Ọlọrun rẹ mú kí Solomoni lókìkí jù ọ́ lọ, kí ìjọba rẹ̀ sì ju tìrẹ lọ.’ Ọba bá tẹríba, ó sì sin Ọlọrun lórí ibùsùn rẹ̀,

48 ó ní ‘Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó jẹ́ kí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi jọba lónìí, tí ó sì jẹ́ kí n fi ojú mi rí i.’ ”

49 Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn tí wọ́n lọ bá Adonija jẹ àsè, gbogbo wọ́n bá dìde, olukuluku bá tirẹ̀ lọ.

50 Ẹ̀rù Solomoni ba Adonija tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, tí ó sì di ìwo pẹpẹ mú.

51 Wọ́n sọ fún Solomoni ọba pé ẹ̀rù rẹ ń ba Adonija ati pé ó wà níbi tí ó ti di ìwo pẹpẹ mú, tí ó sì wí pé, àfi kí Solomoni ọba fi ìbúra ṣèlérí pé kò ní pa òun.

52 Solomoni dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ olóòótọ́, ẹnikẹ́ni kò ní fi ọwọ́ kan ẹyọ kan ninu irun orí rẹ̀, ṣugbọn bí ó bá hùwà ọ̀tẹ̀, yóo kú.”

53 Solomoni ọba bá ranṣẹ lọ mú Adonija wá láti ibi pẹpẹ. Adonija lọ siwaju ọba, ó sì wólẹ̀. Ọba sọ fún un pé kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22