Àwọn Ọba Kinni 14 BM

Ikú Ọmọ Jeroboamu Ọkunrin

1 Ní àkókò yìí Abija, ọmọ Jeroboamu ọba ṣàìsàn,

2 Jeroboamu wí fún aya rẹ̀ pé, “Dìde, kí o yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má lè dá ọ mọ̀ pé aya ọba ni ọ́. Lọ sí Ṣilo níbi tí wolii Ahija tí ó wí fún mi pé n óo jọba Israẹli, ń gbé.

3 Mú burẹdi mẹ́wàá, àkàrà dídùn díẹ̀, ati ìgò oyin kan lọ́wọ́ fún un, yóo sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà fún ọ.”

4 Aya Jeroboamu sì ṣe bí Jeroboamu ti wí. Ó lọ sí ilé wolii Ahija ní Ṣilo. Ogbó ti dé sí Ahija ní àkókò yìí, kò sì ríran mọ́,

5 ṣugbọn OLUWA ti sọ fún un pé aya Jeroboamu ń bọ̀ wá bèèrè ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ̀ tí ó ń ṣàìsàn, OLUWA sì ti sọ ohun tí Ahija yóo sọ fún un.Nígbà tí aya Jeroboamu dé, ó ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni.

6 Ṣugbọn bí Ahija ti gbúròó rẹ̀ tí ó ń wọlé bọ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wọlé, ìwọ aya Jeroboamu. Kí ló dé tí o fi ń ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni ọ́? Ìròyìn burúkú ni mo ní fún ọ.

7 Lọ sọ fún Jeroboamu pé, ‘OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “Mo gbé ọ ga láàrin àwọn eniyan náà, mo sì fi ọ́ jọba lórí Israẹli, àwọn eniyan mi.

8 Mo gba ìjọba lọ́wọ́ ìdílé Dafidi, mo sì fún ọ, o kò ṣe bíi Dafidi, iranṣẹ mi, tí ó pa òfin mi mọ́, tí ó sìn mí tọkàntọkàn, tí ó sì ṣe kìkì ohun tí ó dára lójú mi.

9 Ṣugbọn o ti dá ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú ju ti àwọn tí wọ́n jọba ṣáájú rẹ lọ. O yá ère, o sì dá oniruuru oriṣa láti máa sìn, o mú mi bínú, o sì ti pada lẹ́yìn mi.

10 Nítorí náà, n óo jẹ́ kí ibi bá ìdílé rẹ, n óo sì pa gbogbo ọkunrin inú ìdílé rẹ run, àtẹrú àtọmọ. Bí ìgbà tí eniyan bá sun pàǹtí, tí ó sì jóná ráúráú ni n óo pa gbogbo ìdílé rẹ run.

11 Ajá ni yóo jẹ òkú ẹnikẹ́ni ninu ìdílé rẹ tí ó bá kú láàrin ìlú; ẹni tí ó bá sì kú sinu igbó, ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí.” ’

12 “Nítorí náà, dìde kí o pada sílé, ṣugbọn bí o bá ti ń wọ ìlú, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ náà yóo kú.

13 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọn yóo sì sin ín, nítorí òun nìkan ni wọ́n óo sin ninu ìdílé Jeroboamu, nítorí òun nìkan ni inú OLUWA Ọlọrun Israẹli dùn sí.

14 OLUWA yóo fi ẹnìkan jọba lórí Israẹli tí yóo run ìdílé Jeroboamu lónìí, àní láti ìsinsìnyìí lọ.

15 OLUWA yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà, wọn óo sì máa gbọ̀n bí ewé ojú omi. OLUWA yóo fà wọ́n tu kúrò ninu ilẹ̀ dáradára tí ó fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì fọ́n wọn káàkiri òdìkejì odò Yufurate, nítorí ère oriṣa Aṣerimu tí wọ́n ṣe tí ó mú OLUWA bínú.

16 Yóo kọ Israẹli sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu dá ati èyí tí ó mú kí Israẹli dá pẹlu.”

17 Aya Jeroboamu bá gbéra, ó pada sí Tirisa. Bí ó ti fẹ́ wọlé ni ọmọ tí ń ṣàìsàn náà kú.

18 Àwọn ọmọ Israẹli sin ín, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA gba ẹnu wolii Ahija, iranṣẹ rẹ̀ sọ.

Ikú Jeroboamu

19 Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jeroboamu ọba ṣe: àwọn ogun tí ó jà, ati bí ó ti ṣe ṣe ìjọba rẹ̀, gbogbo rẹ̀ wà ninu ìwé àkọsílẹ̀ Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

20 Jeroboamu jọba fún ọdún mejilelogun. Lẹ́yìn náà, ó kú, wọ́n sì sin ín. Nadabu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Rehoboamu, Ọba Juda

21 Ẹni ọdún mọkanlelogoji ni Rehoboamu ọmọ Solomoni nígbà tí ó gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda, ọdún mẹtadinlogun ni ó fi jọba ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin gbogbo ilẹ̀ Israẹli fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ̀. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀.

22 Àwọn ẹ̀yà Juda ṣẹ̀ sí OLUWA, wọ́n sì ṣe ohun tí ó mú un bínú lọpọlọpọ ju gbogbo àwọn baba ńlá wọn lọ.

23 Nítorí wọ́n kọ́ pẹpẹ ìrúbọ, wọ́n sì ri ọ̀wọ̀n òkúta ati ère oriṣa Aṣerimu mọ́lẹ̀ lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ igi tútù káàkiri.

24 Àwọn ọkunrin tí wọ́n sọ ara wọn di aṣẹ́wó ní ojúbọ àwọn oriṣa náà sì pọ̀ ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe, ni àwọn náà ń ṣe.

25 Ní ọdún karun-un ìjọba Rehoboamu, Ṣiṣaki, ọba Ijipti, gbógun ti Jerusalẹmu.

26 Ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti ààfin ọba pátá; gbogbo apata wúrà tí Solomoni ṣe ni ó kó lọ pẹlu.

27 Rehoboamu bá ṣe apata idẹ dípò wọn. Ó sì fi àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ààfin ọba ṣe alabojuto wọn.

28 Nígbàkúùgbà tí ọba bá ń lọ sinu ilé OLUWA, àwọn ẹ̀ṣọ́ á gbé apata náà tẹ̀lé e, wọn á sì dá wọn pada sinu ilé ìṣúra lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́.

29 Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Rehoboamu ọba ṣe ni a kọ sílẹ̀ ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

30 Ní gbogbo ìgbà ayé Rehoboamu ati ti Jeroboamu ni àwọn mejeeji í máa gbógun ti ara wọn.

31 Rehoboamu jáde láyé, wọ́n sì sin ín sinu ibojì ọba, ní ìlú Dafidi. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀. Abijamu ọmọ rẹ̀ ni ó sì gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22