Àwọn Ọba Kinni 13 BM

1 OLUWA pàṣẹ fún wolii kan, ará Juda, pé kí ó lọ sí Bẹtẹli; nígbà tí ó débẹ̀ ó bá Jeroboamu tí ó dúró níwájú pẹpẹ láti sun turari.

2 Wolii náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ sí pẹpẹ náà, ó ní, “Ìwọ pẹpẹ yìí, ìwọ pẹpẹ yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ó ní, ‘Wò ó! A óo bí ọmọ kan ninu ìdílé Dafidi, orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́ Josaya. Lórí ìwọ pẹpẹ yìí ni yóo ti fi àwọn alufaa oriṣa tí ń sun turari lórí rẹ rúbọ. A óo sì máa sun egungun eniyan lórí rẹ.’ ”

3 Ó sì fún wọn ní àmì kan ní ọjọ́ náà, tí wọn yóo fi mọ̀ pé OLUWA ni ó gba ẹnu òun sọ̀rọ̀. Ó ní, “Pẹpẹ yìí yóo wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ yóo sì fọ́n dànù.”

4 Nígbà tí Jeroboamu gbọ́ ìkìlọ̀ tí wolii Ọlọrun yìí ṣe fún pẹpẹ náà, ó na ọwọ́ sí wolii náà láti ibi pẹpẹ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú un. Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ ọba bá gan, kò sì lè gbé e wálẹ̀ mọ́.

5 Pẹpẹ náà wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ sì fọ́n dànù gẹ́gẹ́ bí wolii náà ti sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA.

6 Jeroboamu ọba bẹ wolii náà pé, “Jọ̀wọ́, bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì gbadura sí i pé kí ó wo apá mi sàn.”Wolii náà bá gbadura sí OLUWA, apá Jeroboamu ọba sì sàn, ó pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

7 Ọba bá sọ fún wolii náà pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé mi kí o lọ jẹun, n óo sì fún ọ ní ẹ̀bùn fún ohun tí o ṣe fún mi.”

8 Ṣugbọn wolii náà dáhùn pé, “Bí o bá tilẹ̀ fẹ́ fún mi ní ìdajì ohun tí o ní, n kò ní bá ọ lọ, n kò ní fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí.

9 Nítorí pé, OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé n kò gbọdọ̀ fẹnu kan nǹkankan ati pé, n kò gbọdọ̀ gba ọ̀nà tí mo gbà wá pada.”

10 Nítorí náà, kò gba ọ̀nà ibi tí ó gbà wá pada, ọ̀nà ibòmíràn ni ó gbà lọ.

Wolii Àgbàlagbà Kan, Ará Bẹtẹli

11 Wolii àgbàlagbà kan wà ní ìlú Bẹtẹli ní ìgbà náà. Àwọn ọmọ wolii náà lọ sọ ohun tí wolii tí ó wá láti Juda ṣe ní Bẹtẹli ní ọjọ́ náà fún baba wọn, ati ohun tí ó sọ fún Jeroboamu ọba.

12 Wolii àgbàlagbà náà bá bi wọ́n pé, “Ọ̀nà ibo ni ó gbà lọ?” Wọ́n sì fi ọ̀nà náà hàn án.

13 Ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ òun ní gàárì, wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì. Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn,

14 ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa wolii ará Juda náà. Ó bá a níbi tí ó jókòó sí lábẹ́ igi Oaku kan, ó bi í pé, ṣe òun ni wolii tí ó wá láti Juda? Ọkunrin náà sì dá a lóhùn pé òun ni.

15 Wolii àgbàlagbà yìí bá wí fún un pé, “Bá mi kálọ sílé, kí o lọ jẹun.”

16 Ṣugbọn wolii ará Juda náà dáhùn pé, “N kò gbọdọ̀ bá ọ pada lọ sí ilé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí.

17 Nítorí OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé, n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun; ati pé, ọ̀nà tí mo bá gbà wá síbí, n kò gbọdọ̀ gbà á pada lọ sílé.”

18 Wolii àgbàlagbà, ará Bẹtẹli náà bá purọ́ fún un pé, “Wolii bíi rẹ ni èmi náà. OLUWA ni ó sì pàṣẹ fún angẹli kan tí ó sọ fún mi pé kí n mú ọ lọ sí ilé, kí n sì fún ọ ní oúnjẹ ati omi.”

19 Wolii ará Juda yìí bá bá wolii àgbàlagbà náà pada lọ sí ilé rẹ̀, ó sì jẹun níbẹ̀.

20 Bí wọ́n ti jóòkó tí wọn ń jẹun, OLUWA bá wolii àgbàlagbà tí ó pè é pada sọ̀rọ̀.

21 Ó bá kígbe mọ́ wolii ará Juda yìí, ó ní, “OLUWA ní, nítorí pé o ti ṣe àìgbọràn sí òun, o kò sì ṣe ohun tí òun OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ.

22 Kàkà bẹ́ẹ̀, o pada, o jẹ, o sì mu ní ibi tí òun ti pàṣẹ pé o kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan. Nítorí náà, o óo kú, wọn kò sì ní sin òkú rẹ sinu ibojì àwọn baba rẹ.”

23 Nígbà tí wọ́n jẹun tan, wolii àgbàlagbà yìí di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní gàárì fún wolii ará Juda.

24 Wolii ará Juda náà bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn, ó ń lọ. Bí ó ti ń lọ lójú ọ̀nà, kinniun kan yọ sí i, ó sì pa á. Òkú rẹ̀ wà ní ojú ọ̀nà níbẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà sì dúró tì í.

25 Àwọn ọkunrin kan tí wọn ń kọjá lọ rí òkú ọkunrin yìí lójú ọ̀nà, ati kinniun tí ó dúró tì í. Wọ́n lọ sí ìlú Bẹtẹli níbi tí wolii àgbàlagbà náà ń gbé, wọ́n sì ròyìn ohun tí wọ́n rí fún un.

26 Nígbà tí wolii àgbàlagbà náà gbọ́, ó ní, “Wolii tí ó ṣàìgbọràn sí ọ̀rọ̀ OLUWA ni. Nítorí náà ni OLUWA fi rán kinniun sí i, pé kí ó pa á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti kìlọ̀ fún un tẹ́lẹ̀.”

27 Ó bá pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ bá mi di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì.” Wọ́n sì bá a di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì.

28 Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ gùn, ó gbọ̀nà, ó sì rí òkú wolii náà nílẹ̀ lójú ọ̀nà, níbi tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà ti dúró tì í. Kinniun yìí kò jẹ òkú rẹ̀ rárá bẹ́ẹ̀ ni kò sì ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ohunkohun.

29 Wolii àgbàlagbà yìí gbé òkú ọkunrin náà sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ó sì gbé e pada wá sí ìlú Bẹtẹli láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ati láti sin ín.

30 Ninu ibojì tirẹ̀ gan-an ni ó sin ín sí. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ó ṣe, arakunrin mi! Arakunrin mi!”

31 Lẹ́yìn ìsìnkú náà, wolii àgbàlagbà yìí sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kú, inú ibojì kan náà ni kí wọn ó sin òun sí, ati pé ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gan-an ni kí wọ́n tẹ́ òkú òun sí.

32 Ó ní, “Nítòótọ́, ọ̀rọ̀ ìbáwí tí OLUWA pàṣẹ pé kí ó sọ sí pẹpẹ Bẹtẹli, ati gbogbo pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà káàkiri ní àwọn ìlú Samaria yóo ṣẹ.”

Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Ó Ṣe Ikú Pa Jeroboamu

33 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Jeroboamu, ọba Israẹli kò yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀. Ṣugbọn ó ń yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù ú láàrin àwọn eniyan ó sì ń fi wọ́n jẹ alufaa ní àwọn ibi pẹpẹ ìrúbọ káàkiri.

34 Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohun tí ó ṣe yìí, ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni ó sì run ìran rẹ̀ lórí oyè, tí wọ́n fi parun patapata lórílẹ̀ ayé.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22