1 Ọpọlọpọ àwọn obinrin àjèjì ni Solomoni fẹ́, lẹ́yìn ọmọ Farao, ọba Ijipti, tí ó kọ́kọ́ fẹ́, ó tún fẹ́ ará Moabu ati ará Amoni, ará Edomu ati ará Sidoni, ati ará Hiti.
2 Solomoni ọba fẹ́ wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli tẹ́lẹ̀, pé wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ fi ọmọ fún wọn; kí àwọn orílẹ̀-èdè náà má baà mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli ṣí sọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn.
3 Ẹẹdẹgbẹrin (700) ni àwọn obinrin ati ọmọ ọba tí Solomoni gbé níyàwó, ó sì tún ní ọọdunrun (300) obinrin mìíràn. Àwọn obinrin náà sì mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun.
4 Nígbà tí Solomoni di àgbàlagbà, àwọn iyawo rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, ó ń bọ àwọn oriṣa àjèjì, kò sì ṣe olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ mọ́, bíi Dafidi, baba rẹ̀.
5 Ó bẹ̀rẹ̀ sí bọ Aṣitoreti, oriṣa àwọn ará Sidoni ati oriṣa Milikomu, ohun ìríra tí àwọn ará Amoni ń bọ.
6 Ohun tí Solomoni ṣe burú lójú OLUWA, kò sì jẹ́ olóòótọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ̀.
7 Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ kan sí orí òkè ní ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu fún oriṣa Kemoṣi, ohun ìríra tí àwọn ará Moabu ń bọ, ati fún oriṣa Moleki, ohun ìríra tí àwọn ará Amoni ń bọ.
8 Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fún gbogbo àwọn iyawo àjèjì tí ó fẹ́, tí wọn ń sun turari, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn oriṣa wọn.
9 Inú bí OLUWA sí Solomoni, nítorí pé, ọkàn rẹ̀ ti yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó fara hàn án nígbà meji,
10 tí ó sì pàṣẹ fún un nítorí ọ̀rọ̀ yìí pé kò gbọdọ̀ bọ oriṣa. Ṣugbọn kò pa òfin OLUWA mọ́.
11 OLUWA bá sọ fún Solomoni pé, “Nítorí pé o ti ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ, o kò pa majẹmu mi mọ́, o kò sì tẹ̀lé ìlànà tí mo pa láṣẹ fún ọ, dájúdájú n óo gba ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, n óo sì fi fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ.
12 Ṣugbọn nítorí ti Dafidi baba rẹ, n kò ní ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí ní àkókò tìrẹ. Ọmọ rẹ ni n óo já ìjọba gbà mọ́ lọ́wọ́.
13 Ṣugbọn n kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, n óo ṣẹ́ ẹ̀yà kan kù sí ọmọ rẹ lọ́wọ́, nítorí ti Dafidi iranṣẹ mi ati ìlú Jerusalẹmu tí mo ti yàn.”
14 OLUWA bá mú kí Adadi dojú ọ̀tá kọ Solomoni; Adadi yìí jẹ́ ìran ọba ní ilẹ̀ àwọn ará Edomu.
15 Ṣáájú àkókò yìí, nígbà tí Dafidi gbógun ti àwọn ará Edomu, tí ó sì ṣẹgun wọn, Joabu balogun rẹ̀ lọ sin àwọn tí wọ́n kú sógun, ó sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin Edomu;
16 nítorí pé Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà ní ilẹ̀ Edomu fún oṣù mẹfa, títí tí ó fi pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Edomu run.
17 Ṣugbọn Adadi ati díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ baba rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ará Edomu sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Adadi kéré pupọ nígbà náà.
18 Adadi ati àwọn iranṣẹ baba rẹ̀ wọnyi kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Ní Parani yìí ni àwọn ọkunrin mìíràn ti para pọ̀ mọ́ wọn, tí gbogbo wọ́n sì jọ lọ sí Ijipti. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Farao, ọba Ijipti, ó fún Adadi ní ilé ati ilẹ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún un déédé.
19 Adadi bá ojurere Farao ọba pàdé, ọba bá fi arabinrin ayaba Tapenesi, iyawo rẹ̀, fún Adadi kí ó fi ṣe aya.
20 Arabinrin ayaba Tapenesi yìí bí ọmọkunrin kan fún Adadi, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Genubati. Inú ilé Farao ọba ni ayaba Tapenesi ti tọ́ ọmọ náà dàgbà, láàrin àwọn ọmọ ọba.
21 Nígbà tí Adadi gbọ́ ní Ijipti pé Dafidi ọba ti kú, ati pé Joabu, balogun rẹ̀ náà ti kú, ó wí fún Farao pé, “Jẹ́ kí n pada lọ sí ìlú mi.”
22 Farao bá bi í léèrè pé, “Kí lo fẹ́ tí o kò rí lọ́dọ̀ mi, tí o fi fẹ́ máa lọ sí ìlú rẹ?”Ṣugbọn Adadi dá a lóhùn pé, “Ṣá jẹ́ kí n máa lọ.”
23 Ọlọrun tún mú kí Resoni ọmọ Eliada dojú ọ̀tá kọ Solomoni, sísá ni Resoni yìí sá kúrò lọ́dọ̀ Hadadeseri, ọba Soba, tí ó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀.
24 Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun Hadadeseri ọba, tí ó sì ti pa àwọn ará Siria tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, Resoni di olórí àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan tí wọ́n kó ara wọn jọ, tí wọn ń gbé Damasku. Àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá fi jọba ní Damasku.
25 Ọ̀tá gidi ni ó jẹ́ fún Israẹli ní ìgbà ayé Solomoni, ó sì ṣe jamba bí Hadadi ti ṣe. Ó kórìíra àwọn ọmọ Israẹli, òun sì ni ọba ilẹ̀ Siria.
26 Ẹnìkan tí ó tún kẹ̀yìn sí Solomoni ni ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ń jẹ́ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ará Sereda, ninu ẹ̀yà Efuraimu, obinrin opó kan tí ń jẹ́ Serua ni ìyá rẹ̀.
27 Ìdí tí ó fi kẹ̀yìn sí Solomoni nìyí:Nígbà tí Solomoni fi ń kún ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu, tí ó sì ń tún odi ìlú náà kọ́,
28 ó ṣe akiyesi Jeroboamu pé ó jẹ́ ọdọmọkunrin tí ó ní akitiyan. Nígbà tí Solomoni rí i bí ó ti ń ṣiṣẹ́ kára kára, ó fi ṣe olórí àwọn tí wọn ń kóni ṣiṣẹ́ tipátipá ní gbogbo agbègbè ẹ̀yà Manase ati Efuraimu.
29 Ní ọjọ́ kan, Jeroboamu ń ti Jerusalẹmu lọ sí ìrìn àjò kan, wolii Ahija, láti Ṣilo sì pàdé òun nìkan lójú ọ̀nà, ninu pápá.
30 Wolii Ahija bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun tí ó wọ̀, ó ya á sí ọ̀nà mejila.
31 Ó fún Jeroboamu ni mẹ́wàá ninu rẹ̀, ó ní, “Gba mẹ́wàá yìí sọ́wọ́, nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n wí fún ọ pé, òun óo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Solomoni òun óo sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ.
32 Ṣugbọn yóo ku ẹ̀yà kan sí ọwọ́ Solomoni, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ati nítorí Jerusalẹmu, ìlú tí òun yàn fún ara òun ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli.
33 Nítorí pé, Solomoni ti kọ òun sílẹ̀, ó sì ń bọ Aṣitoreti, oriṣa àwọn ará Sidoni; ati Kemoṣi, oriṣa àwọn ará Moabu; ati Milikomu oriṣa àwọn ará Amoni. Solomoni kò máa rìn ní ọ̀nà òun OLUWA, kí ó máa ṣe rere, kí ó máa pa òfin òun mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé ìlànà òun bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.
34 Sibẹsibẹ ó ní òun kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ Solomoni, òun óo fi sílẹ̀ láti máa ṣe ìjọba ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ẹni tí òun yàn, tí ó pa òfin òun mọ́, tí ó sì tẹ̀lé ìlànà òun.
35 Ṣugbọn òun óo gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ ọmọ Solomoni, òun óo sì fún ọ ní ẹ̀yà mẹ́wàá.
36 Òun óo fi ẹ̀yà kan sílẹ̀ fún ọmọ rẹ̀, kí ọ̀kan ninu arọmọdọmọ Dafidi, iranṣẹ òun, lè máa jọba nígbà gbogbo ní Jerusalẹmu, ìlú tí òun ti yàn fún ìjọ́sìn ní orúkọ òun.
37 Ó ní ìwọ Jeroboamu ni òun óo mú, tí òun óo sì fi jọba ní Israẹli, o óo sì máa jọba lórí gbogbo agbègbè tí ó bá wù ọ́.
38 Tí o bá fetí sí gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ fún ọ, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà òun, tí ò ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú òun, tí o pa òfin òun mọ́ tí o sì ń mú àṣẹ òun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, iranṣẹ òun ti ṣe, ó ní òun óo wà pẹlu rẹ, arọmọdọmọ rẹ ni yóo máa jọba lẹ́yìn rẹ, òun óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ bí òun ti ṣe fún Dafidi; òun óo sì fi Israẹli fún ọ.
39 Ó ní òun óo jẹ arọmọdọmọ Dafidi níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Solomoni, ṣugbọn kò ní jẹ́ títí ayé.”
40 Nítorí ọ̀rọ̀ yìí, Solomoni ń wá ọ̀nà láti pa Jeroboamu, ṣugbọn Jeroboamu sá lọ sọ́dọ̀ Ṣiṣaki, ọba Ijipti, níbẹ̀ ni ó sì wà títí tí Solomoni fi kú.
41 Àwọn nǹkan yòókù tí Solomoni ṣe: gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ati ọgbọ́n rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìṣe Solomoni.
42 Ogoji ọdún ni ó fi jọba lórí gbogbo Israẹli ní Jerusalẹmu.
43 Nígbà tí ó kú, wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.