1 Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba gbọ́ òkìkí ọgbọ́n Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti fi àwọn ìbéèrè tí ó takókó dán an wò.
2 Ó kó ọpọlọpọ iranṣẹ lẹ́yìn, ó sì di turari olóòórùn dídùn, pẹlu òkúta olówó iyebíye ati ọpọlọpọ wúrà ru ọpọlọpọ ràkúnmí; ó wá sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ patapata fún un.
3 Solomoni dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè rẹ̀, kò sì sí ohunkohun tí ó le fún Solomoni láti ṣàlàyé.
4 Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí Solomoni ti gbọ́n tó, ati irú ààfin tí ó kọ́,
5 irú oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀, ìjókòó àwọn ìjòyè rẹ̀, ìṣesí àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, àwọn tí wọ́n ń gbé ọtí rẹ̀ ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ninu ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ.
6 Ó sọ fún Solomoni ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa ìjọba rẹ ati ọgbọ́n rẹ.
7 Ṣugbọn n kò gbàgbọ́ títí tí mo fi wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Àwọn tí wọ́n sọ fún mi kò tilẹ̀ sọ ìdajì ohun tí mo rí. Ọgbọ́n, ati ọrọ̀ rẹ pọ̀ rékọjá ohun tí mo gbọ́ lọ.
8 Àwọn iyawo rẹ ṣe oríire; bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi tí wọn ń wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo, tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ!
9 Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó sì fi ọ́ jọba Israẹli. Nítorí ìfẹ́ ayérayé tí ó ní sí Israẹli ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn, kí o lè máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo.”
10 Lẹ́yìn náà, ọbabinrin Ṣeba fún Solomoni ọba ní ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà, ati ọpọlọpọ turari olóòórùn dídùn, ati àwọn òkúta olówó iyebíye. Turari tí ọbabinrin Ṣeba fún Solomoni pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé Solomoni kò rí irú rẹ̀ gbà ní ẹ̀bùn mọ́.
11 Àwọn ọkọ̀ ojú omi Hiramu ọba, tí ó kó wúrà wá láti Ofiri kó ọpọlọpọ igi alimugi ati òkúta olówó iyebíye bọ̀ pẹlu.
12 Solomoni ọba fi igi alimugi náà ṣe òpó ilé OLUWA ati ti ààfin rẹ̀. Ó tún lò ninu wọn, ó fi ṣe ohun èlò orin tí wọ́n ń pè ní hapu ati gòjé fún àwọn akọrin rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò rí irú igi alimugi bẹ́ẹ̀ mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí di òní olónìí.
13 Gbogbo ohun tí ọbabinrin Ṣeba fẹ́, tí ó tọrọ lọ́wọ́ Solomoni pátá ni Solomoni fún un, láìka ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n ti kọ́ fi ṣe é lálejò. Ọbabinrin náà pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá pada sí ilẹ̀ wọn.
14 Ọtalelẹgbẹta ó lé mẹfa (666) ìwọ̀n talẹnti wúrà ni ó ń wọlé fún Solomoni ọba lọdọọdun,
15 láìka èyí tí àwọn oníṣòwò ń san fún un, èyí tí ń wá láti ibi òwò rẹ̀, ati èyí tí àwọn ọba Arabia ati àwọn gomina ilẹ̀ Israẹli ń san.
16 Solomoni ṣe igba (200) apata wúrà ńláńlá, wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli.
17 Ó sì tún ṣe ọọdunrun (300) apata wúrà kéékèèké, wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n mina mẹta mẹta. Solomoni ọba kó gbogbo apata wọnyi sinu Ilé Igbó Lẹbanoni.
18 Ó fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì yọ́ wúrà dáradára bò ó.
19 Ìtẹ́ náà ní àtẹ̀gùn mẹfa, ère orí ọmọ mààlúù sì wà lẹ́yìn ìtẹ́ náà. Ère kinniun wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ibi tí wọn ń gbé apá lé lára ìtẹ́ náà.
20 Ère kinniun mejila wà lórí àwọn àtẹ̀gùn mẹfẹẹfa, meji meji lórí àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àtẹ̀gùn náà; kò sí ìjọba orílẹ̀-èdè kankan tí ó tún ní irú ìtẹ́ náà.
21 Wúrà ni wọ́n fi ṣe gbogbo ife ìmumi Solomoni, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí ó wà ninu Ilé Igbó Lẹbanoni. Kò sí ẹyọ kan ninu wọn tí wọ́n fi fadaka ṣe, nítorí pé fadaka kò já mọ́ nǹkankan ní àkókò Solomoni.
22 Ó ní ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi tí wọ́n máa ń bá àwọn ọkọ̀ ojú omi Hiramu lọ sí òkè òkun. Ọdún kẹta kẹta ni wọ́n máa ń pada dé, wọn á sì máa kó ọpọlọpọ wúrà, ati fadaka, eyín erin, ìnàkí, ati ẹyẹ ọ̀kín bọ̀.
23 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe lọ́rọ̀, tí ó sì gbọ́n ju gbogbo ọba yòókù lọ.
24 Gbogbo aráyé a sì máa fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, láti tẹ́tí sí ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un.
25 Ní ọdọọdún ni ọpọlọpọ eniyan máa ń mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn àwọn nǹkan tí wọ́n fi fadaka ati wúrà ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀, pẹlu ẹ̀wù, ati turari olóòórùn dídùn, ẹṣin, ati ìbaaka.
26 Ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin ni Solomoni ọba kó jọ, kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ jẹ́ egbeje (1,400), àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbaafa (1,200). Ó fi apá kan ninu wọn sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn yòókù sí ìlú ńláńlá tí ó ń kó àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sí káàkiri.
27 Solomoni ọba mú kí fadaka pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, igi Kedari sì pọ̀ bí igi Sikamore tí ó wà káàkiri ní Ṣefela ní ẹsẹ̀ òkè Juda.
28 Láti Ijipti ati Kue ni àwọn oníṣòwò Solomoni tií máa bá a ra àwọn ẹṣin wá.
29 Ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni wọ́n máa ń ra kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn oníṣòwò Solomoni níí máa ń tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati àwọn ọba ilẹ̀ Siria.