1 Solomoni gbé ọmọ Farao, ọba Ijipti níyàwó, ó fi bá ọba Farao dá majẹmu àjọṣepọ̀ láàrin wọn. Solomoni mú iyawo náà wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí ààfin rẹ̀ ati ilé OLUWA tí ó ń kọ́, ati odi Jerusalẹmu tí ó ń mọ lọ́wọ́.
2 Oríṣìíríṣìí pẹpẹ ìrúbọ ni àwọn eniyan tẹ́ káàkiri, tí wọ́n sì ń rúbọ lórí wọn, nítorí wọn kò tí ì kọ́ ilé OLUWA nígbà náà.
3 Solomoni fẹ́ràn OLUWA, ó sì ń tẹ̀lé ìlànà Dafidi, baba rẹ̀, ṣugbọn òun náà a máa rúbọ, a sì máa sun turari lórí àwọn pẹpẹ ìrúbọ.
4 Ọba a máa lọ sí Gibeoni láti rúbọ, nítorí pé níbẹ̀ ni pẹpẹ tí ó lókìkí jùlọ nígbà náà wà. A máa fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.
5 OLUWA fara han Solomoni ní ojú àlá ní òru ọjọ́ kan ní Gibeoni, ó sì bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n fún ọ?”
6 Solomoni dá OLUWA lóhùn, ó ní: “O ti fi ìfẹ́ ńlá rẹ, tí kìí yẹ̀ hàn sí Dafidi, baba mi, iranṣẹ rẹ, nítorí pé ó bá ọ lò pẹlu òtítọ́, òdodo ati ọkàn dídúró ṣinṣin. O sì ti fi ìfẹ́ ńlá tí kì í yẹ̀ yìí hàn sí i, o fún un ní ọmọ tí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ lónìí.
7 Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun mi, ìwọ ni o jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ gun orí oyè lẹ́yìn baba mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni mí, n kò sì mọ̀ bí wọ́n ti ń ṣe àkóso.
8 O sì fi èmi iranṣẹ rẹ sí ààrin àwọn eniyan tí o ti yàn fún ara rẹ, àwọn tí wọ́n pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lóǹkà.
9 Nítorí náà, OLUWA, fún èmi iranṣẹ rẹ ní ọgbọ́n láti darí àwọn eniyan rẹ, kí n lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi, nítorí pé, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ni lè ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ báyìí?”
10 Inú OLUWA dùn fún ohun tí Solomoni bèèrè.
11 Ọlọrun sì dá a lóhùn, ó ní, “Nítorí pé ọgbọ́n láti mọ ohun tí ó dára ni o bèèrè, tí o kò bèèrè ẹ̀mí gígùn, tabi ọpọlọpọ ọrọ̀ fún ara rẹ, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ,
12 wò ó! N óo fún ọ ní ohun tí o bèèrè. Ọgbọ́n ati òye tí n óo fún ọ yóo tayọ ti gbogbo àwọn aṣiwaju rẹ, ati ti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ.
13 N óo fún ọ ní ohun tí o kò tilẹ̀ bèèrè. O óo ní ọrọ̀ ati ọlá tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ọba kan tí yóo dàbí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
14 Bí o bá ń gbọ́ tèmi, tí o sì ń pa gbogbo àwọn òfin, ati àwọn ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ ti ṣe, n óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn pẹlu.”
15 Nígbà tí Solomoni tají, ó rí i pé àlá ni òun ń lá, ó bá lọ sí Jerusalẹmu, ó lọ siwaju Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó se àsè ńlá fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀.
16 Ní ọjọ́ kan, àwọn aṣẹ́wó meji kan kó ara wọn wá siwaju Solomoni ọba.
17 Ọ̀kan ninu wọn ní, “Kabiyesi inú ilé kan náà ni èmi ati obinrin yìí ń gbé, ibẹ̀ ló sì wà nígbà tí mo fi bí ọmọkunrin kan.
18 Ọjọ́ kẹta tí mo bí ọmọ tèmi ni obinrin yìí náà bí ọmọkunrin kan. Àwa meji péré ni a wà ninu ilé, kò sí ẹnìkẹta pẹlu wa.
19 Ní alẹ́ ọjọ́ kan, ó sùn lé ọmọ tirẹ̀ mọ́lẹ̀, ọmọ tirẹ̀ bá kú.
20 Ó bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, ó wá jí ọmọ tèmi gbé ní ẹ̀gbẹ́ mi nígbà tí mo sùn lọ, ó tẹ́ ẹ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sọ́dọ̀ mi.
21 Nígbà tí mo jí ní ọjọ́ keji láti fún ọmọ ní oúnjẹ, mo rí i pé ó ti kú. Ṣugbọn nígbà tí mo yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní, mo rí i pé kì í ṣe ọmọ tèmi ni.”
22 Ṣugbọn obinrin keji dáhùn pé, “Rárá! Èmi ni mo ni ààyè ọmọ, òkú ọmọ ni tìrẹ.”Ekinni náà tún dáhùn pé, “Irọ́ ni! Ìwọ ló ni òkú ọmọ, ààyè ọmọ ni tèmi.”Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn níwájú ọba.
23 Nígbà náà ni Solomoni ọba dáhùn, ó ní, “Ekinni keji yín ń wí pé, òun kọ́ ni òun ni òkú ọmọ, ààyè ni tòun.”
24 Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n mú idà kan wá. Nígbà tí wọ́n mú un dé,
25 ó pàṣẹ pé kí wọ́n la ààyè ọmọ sí meji, kí wọ́n sì fún àwọn obinrin mejeeji ní ìdajì, ìdajì.
26 Ọkàn ìyá tí ó ni ààyè ọmọ kò gbà á, nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ọmọ rẹ̀, ó wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbé ààyè ọmọ yìí fún ekeji mi, má pa á rárá.”Ṣugbọn èyí ekeji dáhùn pé, “Rárá! Kò ní jẹ́ tèmi, kò sì ní jẹ́ tìrẹ. Jẹ́ kí wọ́n là á sí meji.”
27 Ọba dáhùn, ó ní, “Ẹ má pa ààyè ọmọ yìí rárá, ẹ gbé e fún obinrin àkọ́kọ́. Òun gan-an ni ìyá rẹ̀.”
28 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ irú ìdájọ́ tí Solomoni ọba dá yìí, ó mú kí ó túbọ̀ níyì lójú wọn; nítorí wọ́n mọ̀ pé Ọlọrun ni ó fún un ní ọgbọ́n láti ṣe ìdájọ́ ní irú ọ̀nà ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀.