Àwọn Ọba Kinni 12 BM

Àwọn Ẹ̀yà Apá Ìhà Àríwá Dìtẹ̀, Wọ́n Sì Ya

1 Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ níbẹ̀ láti fi jọba.

2 Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ìròyìn yìí ní Ijipti, (níbẹ̀ ni ó ń gbé láti ìgbà tí ó ti sá lọ fún Solomoni ọba), ó pada wá sílé láti Ijipti.

3 Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ pè é, òun ati gbogbo wọ́n sì tọ Rehoboamu lọ, wọ́n wí fún un pé,

4 “Àjàgà wúwo ni Solomoni baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn. Ṣugbọn bí o bá dín iṣẹ́ líle baba rẹ yìí kù, tí o sì mú kí ìgbé ayé rọ̀ wá lọ́rùn, a óo máa sìn ọ́.”

5 Rehoboamu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ná, lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, ẹ pada wá gbọ́ èsì.” Àwọn eniyan náà bá pada lọ.

6 Rehoboamu ọba bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n jẹ́ olùdámọ̀ràn Solomoni baba rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀, ó bi wọ́n léèrè pé, “Irú ìdáhùn wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?”

7 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe bí iranṣẹ fún àwọn eniyan wọnyi lónìí, tí o sì sìn wọ́n, tí o sì fún wọn ní èsì rere sí ìbéèrè tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ ni wọn óo máa sìn títí lae.”

8 Ṣugbọn ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jíròrò pẹlu àwọn ọdọmọkunrin, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọ́n wà ní ààfin pẹlu rẹ̀.

9 Ó bi wọ́n léèrè, ó ní, “Kí ni ìmọ̀ràn tí ẹ lè gbà mí, lórí irú ìdáhùn tí a le fún àwọn eniyan tí wọ́n ní kí n dín ẹrù wúwo tí baba mi dì lé àwọn lórí kù?”

10 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ohun tí o óo wí fún àwọn tí wọ́n ní baba rẹ di ẹrù wúwo lé àwọn lórí, ṣugbọn kí o bá àwọn dín ẹrù yìí kù ni pé ìka ọwọ́ rẹ tí ó kéré jùlọ tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba rẹ lọ.

11 Sọ fún wọn pé, ‘Ṣé ẹ sọ pé ẹrù wúwo ni baba mi dì rù yín? Tèmi tí n óo dì rù yín yóo tilẹ̀ tún wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ; ati pé ẹgba ni baba mi fi ń nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.’ ”

12 Jeroboamu ati gbogbo àwọn eniyan náà bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wọn.

13 Rehoboamu gbójú mọ́ àwọn eniyan náà bí ó ti ń dá wọn lóhùn, ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un,

14 gẹ́gẹ́ bí àwọn ọdọmọkunrin ti gbà á nímọ̀ràn. Ó ní, “Ẹrù wúwo ni ẹ sọ pé baba mi dì rù yín, ṣugbọn èmi yóo tilẹ̀ tún dì kún un ni. Ẹgba ni ó fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.”

15 Nítorí náà, ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé OLUWA alára ni ó fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí rí bẹ́ẹ̀, kí ọ̀rọ̀ OLUWA lè ṣẹ, tí ó bá Jeroboamu ọmọ Nebati sọ, láti ẹnu wolii Ahija ará Ṣilo.

16 Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé, ọba kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dá a lóhùn pé,“Kí ló kàn wá pẹlu ìdílé Dafidi?Kí ló dà wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese?Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ pada sílé yín,kí Dafidi máa bojútó ilé rẹ̀!”

17 Gbogbo Israẹli bá pada sílé wọn; ṣugbọn Rehoboamu ń jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Juda.

18 Lẹ́yìn náà, Rehoboamu ọba rán Adoniramu, tí ó jẹ́ ọ̀gá àgbà àwọn tí wọn ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́ tipátipá, láti lọ bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Rehoboamu bá múra kíá, ó bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá lọ sí Jerusalẹmu.

19 Láti ìgbà náà ni Israẹli ti ń bá ìdílé Dafidi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní yìí.

20 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé Jeroboamu ti pada dé láti ilẹ̀ Ijipti, wọ́n pè é sí ibi ìpàdé kan tí wọ́n ṣe, wọ́n sì fi jọba Israẹli. Kò sí ẹni tí ó tẹ̀lé ìdílé Dafidi, àfi ẹ̀yà Juda nìkan ṣoṣo.

Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣemaaya

21 Nígbà tí Rehoboamu pada dé Jerusalẹmu, ó ṣa ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ láti inú ẹ̀yà Juda ati ti Bẹnjamini, láti lọ gbógun ti ilé Israẹli kí wọ́n sì gba ìjọba ìhà àríwá Israẹli pada fún un.

22 Ṣugbọn Ọlọrun sọ fún wolii Ṣemaaya,

23 pé kí ó jíṣẹ́ fún Rehoboamu, ọba Juda ati gbogbo ẹ̀yà Juda ati ti Bẹnjamini,

24 pé OLUWA ni wọn kò gbọdọ̀ gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé arakunrin wọn ni wọ́n, ati pé kí olukuluku pada sí ilé rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ òun Ọlọrun ni ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Nítorí náà gbogbo wọ́n gba ohun tí OLUWA pa láṣẹ, wọ́n sì pada sí ilé wọn bí OLUWA ti wí.

Jeroboamu Yipada Kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun

25 Jeroboamu ọba Israẹli mọ odi yí ìlú Ṣekemu, tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ká, ó sì ń gbé ibẹ̀. Lẹ́yìn náà, láti Ṣekemu ó lọ mọ odi yí ìlú Penueli ká.

26 Nígbà tí ó yá, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìjọba yìí yóo pada di ti ilé Dafidi.”

27 Ó ní, “Bí àwọn eniyan wọnyi bá ń lọ rúbọ ní ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, ọkàn gbogbo wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ pada sẹ́yìn Rehoboamu, oluwa wọn; wọn óo sì pa mí, wọn óo sì pada tọ Rehoboamu, ọba Juda, lọ.”

28 Jeroboamu lọ gba àmọ̀ràn, ó bá fi wúrà yá ère akọ mààlúù meji, ó sì wí fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ó pẹ́ tí ẹ ti ń lọ rúbọ ní Jerusalẹmu. Ó tó gẹ́ẹ́! Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.”

29 Ó gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní ìlú Bẹtẹli ó sì gbé ekeji sí ìlú Dani.

30 Ọ̀rọ̀ yìí di ẹ̀ṣẹ̀ sí wọn lọ́rùn nítorí pé àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìlú Bẹtẹli ati ìlú Dani láti jọ́sìn.

31 Jeroboamu tún kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sí orí òkè káàkiri, ó sì yan àwọn eniyan ninu gbogbo ìdílé tí kì í ṣe ìran ẹ̀yà Lefi, láti máa ṣiṣẹ́ alufaa.

Ọlọrun Lòdì sí Ìsìn Bẹtẹli

32 Jeroboamu ya ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún ilẹ̀ Juda, ó sì rúbọ lórí pẹpẹ sí akọ mààlúù tí ó fi wúrà ṣe ní ìlú Bẹtẹli. Ó fi àwọn alufaa kan sibẹ, láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa ninu àwọn ilé ìsìn tí ó kọ́ sibẹ.

33 Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ tíí ṣe ọjọ́ tí ó yàn fún ara rẹ̀, ó lọ sí ibi pẹpẹ tí ó kọ́ sí ìlú Bẹtẹli láti rúbọ. Ó yan àjọ̀dún fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì lọ sun turari lórí pẹpẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22