Àwọn Ọba Kinni 18 BM

Elija ati Àwọn Wolii Baali

1 Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, ní ọdún kẹta tí ọ̀dá ti dá, OLUWA sọ fún Elija pé, “Lọ fi ara rẹ han Ahabu ọba, n óo sì rọ̀jò sórí ilẹ̀.”

2 Elija bá lọ fi ara han Ahabu.Ìyàn tí ó mú ní ìlú Samaria pọ̀ pupọ.

3 Ahabu pe Ọbadaya, tí ó jẹ́ alabojuto ààfin. Ọbadaya jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA gan-an.

4 Nígbà tí Jesebẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn wolii OLUWA, Ọbadaya yìí ló kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, ó kó aadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi.

5 Ahabu sọ fún Ọbadaya pé, “Lọ wo gbogbo orísun omi ati àfonífojì ní gbogbo ilẹ̀ yìí, kí o wò ó bóyá a lè rí koríko láti fi bọ́ àwọn ẹṣin ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kí wọ́n má baà kú.”

6 Wọ́n ṣe àdéhùn ibi tí olukuluku yóo lọ wò ní gbogbo ilẹ̀ náà, olukuluku sì gba ọ̀nà tirẹ̀ lọ. Ahabu ọba lọ sí apá kan, Ọbadaya sì lọ sí apá keji.

7 Bí Ọbadaya ti ń lọ, lójijì ni ó pàdé Elija. Ó ranti rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì bi í léèrè pé, “Àbí ìwọ kọ́ ni, Elija, oluwa mi?”

8 Elija dá a lóhùn pé, “Èmi ni, lọ sọ fún oluwa rẹ, ọba, pé èmi Elija wà níhìn-ín.”

9 Ọbadaya bá bèèrè pé, “Kí ni mo ṣe, tí o fi fẹ́ fa èmi iranṣẹ rẹ, lé Ahabu ọba lọ́wọ́ láti pa?

10 OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, pé ọba ti wá ọ káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Bí ọba ìlú kan, tabi tí orílẹ̀-èdè kan, bá sọ pé o kò sí ní ilẹ̀ òun, Ahabu á ní dandan, àfi kí wọ́n búra pé lóòótọ́ ni wọn kò rí ọ.

11 Nisinsinyii, o wá sọ fún mi pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín.

12 Bí mo bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ tán tí ẹ̀mí Ọlọrun bá gbé ọ lọ sí ibi tí n kò mọ̀ ńkọ́? Bí mo bá lọ sọ fún Ahabu pé o wà níhìn-ín, tí kò bá rí ọ mọ́, pípa ni yóo pa mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà èwe mi ni mo ti bẹ̀rù OLUWA.

13 Àbí o kò gbọ́ nígbà tí Jesebẹli ń pa àwọn wolii OLUWA, pé mo kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, mo kó araadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, mo sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi.

14 O ṣe wá sọ pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín? Pípa ni yóo pa mí.”

15 Elija dá a lóhùn pé, “Ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí mò ń sìn, mo ṣèlérí fún ọ pé, n óo fara han ọba lónìí.”

16 Ọbadaya bá lọ sọ fún ọba, ọba sì lọ pàdé Elija.

17 Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó wí fún un pé, “Ojú rẹ nìyí ìwọ tí ò ń yọ Israẹli lẹ́nu!”

18 Elija dáhùn pé, “Èmi kọ́ ni mò ń yọ Israẹli lẹ́nu, ìwọ gan-an ni. Ìwọ ati ilé baba rẹ; nítorí ẹ ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, ẹ sì ń sin oriṣa Baali.

19 Nítorí náà, pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí wọ́n pàdé mi ní orí òkè Kamẹli. Kí aadọtalenirinwo (450) àwọn wolii oriṣa Baali ati àwọn irinwo (400) wolii oriṣa Aṣera, tí ayaba Jesebẹli ń bọ náà bá wọn wá.”

20 Ahabu bá ranṣẹ pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ati àwọn wolii oriṣa Baali, pé kí wọ́n pàdé òun ní orí òkè Kamẹli.

21 Elija bá súnmọ́ gbogbo àwọn eniyan, ó wí fún wọn pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi máa ṣe iyèméjì? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni Ọlọrun, ẹ máa sìn ín. Bí ó bá sì jẹ́ pé oriṣa Baali ni ẹ máa bọ ọ́.” Ṣugbọn àwọn eniyan náà kò sọ ohunkohun.

22 Elija tún sọ fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni wolii OLUWA tí ó ṣẹ́kù, ṣugbọn àwọn wolii oriṣa Baali tí wọ́n wà jẹ́ aadọtalenirinwo (450).

23 Ẹ fún wa ní akọ mààlúù meji, kí àwọn wolii Baali mú ọ̀kan, kí wọ́n pa á, kí wọ́n sì gé e kéékèèké. Kí wọ́n kó o sórí igi, ṣugbọn kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà yóo pa akọ mààlúù keji, n óo kó o sórí igi, n kò sì ní fi iná sí i.

24 Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin ẹ ké pe oriṣa Baali, Ọlọrun yín, èmi náà yóo sì ké pe OLUWA. Èyíkéyìí ninu wọn tí ó bá dáhùn, tí ó bá mú kí iná ṣẹ́, òun ni Ọlọrun.”Àwọn eniyan náà bá pariwo pé, “A gbà bẹ́ẹ̀.”

25 Elija bá sọ fún àwọn wolii Baali pé, “Ẹ̀yin ni ẹ pọ̀, ẹ̀yin ẹ kọ́kọ́ mú akọ mààlúù kan, kí ẹ tọ́jú rẹ̀. Ẹ gbadura sí oriṣa yín ṣugbọn ẹ má fi iná sí igi ẹbọ yín.”

26 Wọ́n mú akọ mààlúù tí wọ́n fún wọn, wọ́n pa á, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa Baali láti àárọ̀ títí di ọ̀sán. Wọ́n ń wí pé, “Baali, dá wa lóhùn!” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fọhùn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jó yípo pẹpẹ tí wọ́n kọ́. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá wọn lóhùn.

27 Nígbà tí ó di ọ̀sán, Elija bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé, “Ẹ kígbe sókè, nítorí pé Ọlọrun ṣá ni. Bóyá ó ronú lọ ni, bóyá ó sì wọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lọ ni; tabi ó lè jẹ́ pé ó lọ sí ìrìn àjò ni. Bóyá ó sùn ni, ẹ sì níláti jí i.”

28 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe sókè, wọ́n ń fi idà ati ọ̀kọ̀ ya ara wọn lára, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi bò wọ́n.

29 Nígbà tí ọ̀sán pọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń sáré kiri bíi wèrè, títí tí ó fi di àkókò ìrúbọ ọ̀sán, ṣugbọn Baali kò dá wọn lóhùn rárá. Kò tilẹ̀ fọhùn.

30 Nígbà tó yá, Elija wí fún gbogbo àwọn eniyan náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi níhìn-ín.” Gbogbo wọn súnmọ́ ọn, wọ́n sì yí i ká. Ó bá tún pẹpẹ OLUWA tí ó ti wó ṣe.

31 Ó kó òkúta mejila jọ, òkúta kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jakọbu, ẹni tí OLUWA sọ fún pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.”

32 Ó fi òkúta mejeejila náà kọ́ pẹpẹ ní orúkọ OLUWA. Ó gbẹ́ kòtò kan yí pẹpẹ náà ká, kòtò náà tóbi tó láti gba òṣùnwọ̀n irúgbìn meji (nǹkan bíi lita mẹrinla).

33 Lẹ́yìn náà, ó to igi sórí pẹpẹ, ó gé akọ mààlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì tò wọ́n sórí igi. Ó ní kí wọ́n pọn ẹ̀kún ìkòkò omi ńlá mẹrin, kí wọ́n dà á sórí ẹbọ ati igi náà, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.

34 Ó ní kí wọ́n tún da mẹrin mìíràn, wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní kí wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹẹkẹta, wọ́n sì tún ṣe bẹ́ẹ̀.

35 Omi náà ṣàn sílẹ̀ yí pẹpẹ ká, ó sì kún kòtò tí wọ́n gbẹ́ yípo.

36 Nígbà tí ó di àkókò ìrúbọ ìrọ̀lẹ́, Elija súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó sì gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Israẹli, fi hàn lónìí pé ìwọ ni Ọlọrun Israẹli, ati pé iranṣẹ rẹ ni mí, ati pé gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, pẹlu àṣẹ rẹ ni.

37 Dá mi lóhùn, OLUWA, dá mi lóhùn; kí àwọn eniyan wọnyi lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA ni Ọlọrun, ati pé ìwọ ni o fẹ́ yí ọkàn wọn pada sọ́dọ̀ ara rẹ.”

38 OLUWA bá sọ iná sílẹ̀, iná náà sì jó ẹbọ náà ati igi, ati òkúta. Ó jó gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀, ó sì lá gbogbo omi tí ó wà ninu kòtò.

39 Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n wí pé, “OLUWA ni Ọlọrun! OLUWA ni Ọlọrun!”

40 Elija bá pàṣẹ pé, “Ẹ mú gbogbo àwọn wolii oriṣa Baali! Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wọn sá lọ.” Àwọn eniyan náà bá ki gbogbo wọn mọ́lẹ̀, Elija kó wọn lọ sí ibi odò Kiṣoni, ó sì pa wọ́n sibẹ.

Ọ̀dá Parí

41 Lẹ́yìn náà, Elija sọ fún Ahabu ọba pé, “Lọ, jẹun, kí o wá nǹkan mu, nítorí mo gbọ́ kíkù òjò.”

42 Nígbà tí Ahabu lọ jẹun, Elija gun orí òkè Kamẹli lọ, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì ki orí bọ ààrin orúnkún rẹ̀ mejeeji.

43 Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ wo apá ìhà òkun.Iranṣẹ náà lọ, ó sì pada wá, ó ní, òun kò rí nǹkankan. Elija sọ fún un pé, “Tún lọ ní ìgbà meje.”

44 Ní ìgbà keje tí ó pada dé, ó ní, “Mo rí ìkùukùu kan tí ń bọ̀ láti inú òkun, ṣugbọn kò ju àtẹ́lẹwọ́ lọ.”Elija pàṣẹ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ sọ fún ọba, kí ó kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, kí ó sì sọ̀kalẹ̀ pada sí ilé kí òjò má baà ká a mọ́ ibi tí ó wà.

45 Láìpẹ́, ìkùukùu bo gbogbo ojú ọ̀run, afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́, òjò ńlá sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ahabu kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì pada lọ sí Jesireeli.

46 Agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí Elija, ó di àmùrè rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ; ó sì ṣáájú Ahabu dé ẹnubodè Jesireeli.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22