14 ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa wolii ará Juda náà. Ó bá a níbi tí ó jókòó sí lábẹ́ igi Oaku kan, ó bi í pé, ṣe òun ni wolii tí ó wá láti Juda? Ọkunrin náà sì dá a lóhùn pé òun ni.
15 Wolii àgbàlagbà yìí bá wí fún un pé, “Bá mi kálọ sílé, kí o lọ jẹun.”
16 Ṣugbọn wolii ará Juda náà dáhùn pé, “N kò gbọdọ̀ bá ọ pada lọ sí ilé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí.
17 Nítorí OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé, n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun; ati pé, ọ̀nà tí mo bá gbà wá síbí, n kò gbọdọ̀ gbà á pada lọ sílé.”
18 Wolii àgbàlagbà, ará Bẹtẹli náà bá purọ́ fún un pé, “Wolii bíi rẹ ni èmi náà. OLUWA ni ó sì pàṣẹ fún angẹli kan tí ó sọ fún mi pé kí n mú ọ lọ sí ilé, kí n sì fún ọ ní oúnjẹ ati omi.”
19 Wolii ará Juda yìí bá bá wolii àgbàlagbà náà pada lọ sí ilé rẹ̀, ó sì jẹun níbẹ̀.
20 Bí wọ́n ti jóòkó tí wọn ń jẹun, OLUWA bá wolii àgbàlagbà tí ó pè é pada sọ̀rọ̀.