Àwọn Ọba Kinni 13:27-33 BM

27 Ó bá pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ bá mi di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì.” Wọ́n sì bá a di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì.

28 Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ gùn, ó gbọ̀nà, ó sì rí òkú wolii náà nílẹ̀ lójú ọ̀nà, níbi tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà ti dúró tì í. Kinniun yìí kò jẹ òkú rẹ̀ rárá bẹ́ẹ̀ ni kò sì ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ohunkohun.

29 Wolii àgbàlagbà yìí gbé òkú ọkunrin náà sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ó sì gbé e pada wá sí ìlú Bẹtẹli láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ati láti sin ín.

30 Ninu ibojì tirẹ̀ gan-an ni ó sin ín sí. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ó ṣe, arakunrin mi! Arakunrin mi!”

31 Lẹ́yìn ìsìnkú náà, wolii àgbàlagbà yìí sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kú, inú ibojì kan náà ni kí wọn ó sin òun sí, ati pé ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gan-an ni kí wọ́n tẹ́ òkú òun sí.

32 Ó ní, “Nítòótọ́, ọ̀rọ̀ ìbáwí tí OLUWA pàṣẹ pé kí ó sọ sí pẹpẹ Bẹtẹli, ati gbogbo pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà káàkiri ní àwọn ìlú Samaria yóo ṣẹ.”

33 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Jeroboamu, ọba Israẹli kò yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀. Ṣugbọn ó ń yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù ú láàrin àwọn eniyan ó sì ń fi wọ́n jẹ alufaa ní àwọn ibi pẹpẹ ìrúbọ káàkiri.