Àwọn Ọba Kinni 18:27-33 BM

27 Nígbà tí ó di ọ̀sán, Elija bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé, “Ẹ kígbe sókè, nítorí pé Ọlọrun ṣá ni. Bóyá ó ronú lọ ni, bóyá ó sì wọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lọ ni; tabi ó lè jẹ́ pé ó lọ sí ìrìn àjò ni. Bóyá ó sùn ni, ẹ sì níláti jí i.”

28 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe sókè, wọ́n ń fi idà ati ọ̀kọ̀ ya ara wọn lára, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi bò wọ́n.

29 Nígbà tí ọ̀sán pọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń sáré kiri bíi wèrè, títí tí ó fi di àkókò ìrúbọ ọ̀sán, ṣugbọn Baali kò dá wọn lóhùn rárá. Kò tilẹ̀ fọhùn.

30 Nígbà tó yá, Elija wí fún gbogbo àwọn eniyan náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi níhìn-ín.” Gbogbo wọn súnmọ́ ọn, wọ́n sì yí i ká. Ó bá tún pẹpẹ OLUWA tí ó ti wó ṣe.

31 Ó kó òkúta mejila jọ, òkúta kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jakọbu, ẹni tí OLUWA sọ fún pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.”

32 Ó fi òkúta mejeejila náà kọ́ pẹpẹ ní orúkọ OLUWA. Ó gbẹ́ kòtò kan yí pẹpẹ náà ká, kòtò náà tóbi tó láti gba òṣùnwọ̀n irúgbìn meji (nǹkan bíi lita mẹrinla).

33 Lẹ́yìn náà, ó to igi sórí pẹpẹ, ó gé akọ mààlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì tò wọ́n sórí igi. Ó ní kí wọ́n pọn ẹ̀kún ìkòkò omi ńlá mẹrin, kí wọ́n dà á sórí ẹbọ ati igi náà, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.