Àwọn Ọba Kinni 20:13-19 BM

13 Wolii kan bá tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Ṣé o rí gbogbo àwọn ọmọ ogun yìí bí wọ́n ti pọ̀ tó? Wò ó! N óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn lónìí, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

14 Ahabu bèèrè pé, “Ta ni yóo ṣáájú ogun?”Wolii náà dáhùn pé, “OLUWA ní, àwọn iranṣẹ gomina ìpínlẹ̀ ni.”Ahabu tún bèèrè pé, “Ta ni yóo bẹ̀rẹ̀ ogun náà?”Wolii náà dáhùn pé, “Ìwọ gan-an ni.”

15 Ọba bá pe gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn gomina ìpínlẹ̀ jọ, gbogbo wọn jẹ́ ojilerugba ó dín mẹjọ (232), ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, gbogbo wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin (7,000).

16 Nígbà tí ó di ọ̀sán, wọ́n kó ogun jáde, bí Benhadadi ọba ati àwọn ọba mejilelọgbọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ti ń mu ọtí àmupara ninu àgọ́ wọn.

17 Àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun Israẹli, wọ́n bá lọ ṣígun bá Benhadadi. Àwọn amí tí ọba Benhadadi rán jáde lọ ròyìn fún un pé, àwọn eniyan kan ń jáde bọ̀ láti ìlú Samaria.

18 Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n ìbáà máa bọ̀ wá jagun, wọn ìbáà sì máa bọ̀ wá sọ̀rọ̀ alaafia.

19 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun ṣe jáde ní ìlú: àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun, lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli tẹ̀lé wọn.