4 Ó bi Jehoṣafati pé, “Ṣé o óo bá mi lọ, kí á jọ lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi?”Jehoṣafati bá dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ti yá ọ, ó yá mi. Tìrẹ ni àwọn eniyan mi, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹṣin mi pẹlu.”
5 Jehoṣafati fi ṣugbọn kan kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a kọ́kọ́ wádìí lọ́wọ́ OLUWA ná.”
6 Ahabu ọba Israẹli bá pe àwọn wolii bí irinwo (400) jọ, ó bi wọ́n pé ṣé kí òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi àbí kí òun má lọ?Wọ́n dá a lóhùn pé, “Máa lọ, nítorí OLUWA yóo jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́, yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀.”
7 Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè pé, “Ṣé kò tún sí wolii OLUWA mìíràn mọ́, tí a lè wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀?”
8 Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.”Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.”
9 Ahabu bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ní ààfin pé kí ó lọ pe Mikaaya, ọmọ Imila, wá kíákíá.
10 Ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda wọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì jókòó lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà tí ó wà lẹ́nu bodè Samaria; gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.