1 Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà.
2 Ilẹ̀ tí ó kù nìwọ̀nyí: gbogbo agbègbè àwọn ará Filistia ati ti Geṣuri;
3 láti odò Ṣihori, ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ijipti, títí lọ sí apá àríwá ní ààlà Ekironi tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kenaani, (Marun-un ni ọba àwọn ará Filistia, àwọn nìwọ̀nyí: ọba Gasa, ti Aṣidodu, ti Aṣikeloni, ti Gati, ati ti Ekironi) ati ilẹ̀ àwọn Afimu ní ìhà gúsù.
4 Lẹ́yìn náà, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Meara, tíí ṣe ilẹ̀ àwọn ará Sidoni, títí dé Afeki ní ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amori,
5 ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati.
6 Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín.
7 Ẹ pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an yòókù ati ìdajì ẹ̀yà Manase.”