Joṣua 3 BM

Àwọn Ọmọ Israẹli La Odò Jọdani Kọjá

1 Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbéra ní Akasia lọ sí etí odò Jọdani, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀ kí wọn tó la odò náà kọjá.

2 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, gbogbo àwọn olórí wọn lọ káàkiri àgọ́ náà.

3 Wọ́n pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i pé, àwọn alufaa, ọmọ Lefi gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, kí ẹ̀yin náà gbéra, kí ẹ sì tẹ̀lé wọn.

4 Kí ẹ lè mọ ọ̀nà tí ẹ óo gbà, nítorí pé ẹ kò rin ọ̀nà yìí rí. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ súnmọ́ Àpótí Majẹmu náà jù, ẹ gbọdọ̀ fi àlàfo tí ó tó nǹkan bí ẹgbaa (2,000) igbọnwọ sílẹ̀ láàrin ẹ̀yin ati Àpótí Majẹmu náà.”

5 Joṣua sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nítorí pé OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin yín ní ọ̀la.”

6 Joṣua bá sọ fún àwọn alufaa pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu náà kí ẹ sì máa lọ níwájú àwọn eniyan yìí.” Wọ́n bá gbé Àpótí Majẹmu náà, wọ́n sì ń lọ níwájú wọn.

7 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Lónìí ni n óo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè mọ̀ pé bí mo ti wà pẹlu Mose, bẹ́ẹ̀ ni n óo wà pẹlu rẹ.

8 Pàṣẹ fún àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí odò Jọdani, ẹ wọ inú odò lọ, kí ẹ sì dúró níbẹ̀.’ ”

9 Joṣua bá pe àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun yín wí.

10 Èyí ni ẹ óo fi mọ̀ pé Ọlọrun alààyè wà láàrin yín, kò sì ní kùnà láti lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi, àwọn ará Perisi, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Jebusi, jáde fun yín.

11 Wò ó! Wọn yóo gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé kọjá níwájú yín sinu odò Jọdani.

12 Nítorí náà, ẹ yan àwọn ọkunrin mejila ninu ẹ̀yà Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

13 Nígbà tí ẹsẹ̀ àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé bá kan odò Jọdani, odò náà yóo dúró; kò ní ṣàn mọ́, gbogbo omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè yóo sì wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá.”

14 Nígbà náà ni àwọn eniyan náà gbéra ninu àgọ́ wọn láti la odò Jọdani kọjá pẹlu àwọn alufaa tí wọn ń gbé Àpótí Majẹmu lọ níwájú wọn,

15 (àkókò náà jẹ́ àkókò ìkórè, odò Jọdani sì kún dé ẹnu), ṣugbọn bí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu ti dé etídò náà, tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ wọn kan omi,

16 omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá ní òkèèrè ní ìlú Adamu tí ó wà lẹ́bàá Saretani. Èyí tí ó ń ṣàn lọ sí Òkun Araba tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀ gé kúrò, ó sì dá dúró. Àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì ìlú Jẹriko.

17 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá lọ lórí ilẹ̀ gbígbẹ, àwọn alufaa tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA dúró lórí ilẹ̀ gbígbẹ láàrin odò Jọdani, títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi la odò Jọdani kọjá.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24