Joṣua 11 BM

Joṣua Ṣẹgun Jabini ati Àwọn tí Wọ́n Darapọ̀ Mọ́ ọn

1 Nígbà tí Jabini ọba Hasori, gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ranṣẹ sí Jobabu, ọba Madoni, ati sí ọba Ṣimironi, ati sí ọba Akiṣafu,

2 ati sí àwọn ọba tí wọ́n wà ní àwọn ìlú olókè ti apá ìhà àríwá, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Araba ní ìhà gúsù Kineroti, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Nafoti-dori ní apá ìwọ̀ oòrùn.

3 Ó ranṣẹ sí àwọn ará Kenaani ní ìhà ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Jebusi ní àwọn agbègbè olókè, ati àwọn ará Hifi tí wọ́n wà ní abẹ́ òkè Herimoni ní ilẹ̀ Misipa.

4 Gbogbo wọn jáde pẹlu gbogbo ọmọ ogun wọn, wọ́n pọ̀ yanturu bí eṣú. Wọ́n dàbí iyanrìn etí òkun. Ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò lóǹkà.

5 Gbogbo àwọn ọba wọnyi parapọ̀, wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n sì pàgọ́ sí etí odò Meromu.

6 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí pé ní ìwòyí ọ̀la, òkú wọn ni n óo fi lé Israẹli lọ́wọ́. Dídá ni kí ẹ dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

7 Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá jálù wọ́n lójijì ní etí odò Meromu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn jagun.

8 OLUWA fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Wọ́n lé wọn títí dé Sidoni ati Misirefoti Maimu, ati apá ìlà oòrùn títí dé àfonífojì Misipa, wọ́n pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.

9 Joṣua ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí ó ṣe sí wọn: ó dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, ó sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn níná.

10 Joṣua bá yipada, ó gba ìlú Hasori, ó sì fi idà pa ọba wọn, nítorí pé Hasori ni olú-ìlú ìjọba ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ rí.

11 Wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà láìku ẹyọ ẹnìkan, wọ́n sì sun ìlú Hasori níná.

12 Joṣua gba gbogbo ìlú àwọn ọba náà, ó kó àwọn ọba wọn, ó fi idà pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún un.

13 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò sun èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí wọ́n kọ́ sórí òkítì níná, àfi Hasori nìkan ni Joṣua dáná sun.

14 Àwọn ọmọ Israẹli kó gbogbo dúkìá ìlú náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní ìkógun, ṣugbọn wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ run patapata, wọn kò dá ẹyọ ẹnìkan sí.

15 Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, iranṣẹ rẹ̀, ni Mose náà ṣe pàṣẹ fún Joṣua, tí Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ohunkohun sílẹ̀ láìṣe, ninu gbogbo nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.

Àwọn Ilẹ̀ Tí Joṣua Gbà

16 Gbogbo ilẹ̀ náà ni Joṣua gbà: ó gba àwọn agbègbè olókè, àwọn tí wọ́n wà ní Nẹgẹbu, gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ Goṣeni, àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, àwọn tí ó wà ní Araba, ati gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí àwọn òkè Israẹli ati ẹsẹ̀ òkè rẹ̀.

17 Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n.

18 Joṣua bá àwọn ọba wọnyi jagun fún ìgbà pípẹ́.

19 Kò sí ìlú tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia àfi àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé ìlú Gibeoni. Gbogbo àwọn yòókù patapata ni wọ́n kó lójú ogun.

20 Nítorí pé, OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n sì gbógun ti Israẹli, kí àwọn ọmọ Israẹli lè pa wọ́n run, kí wọ́n má baà ṣàánú wọn, ṣugbọn kí wọ́n pa wọ́n run gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

21 Ní àkókò yìí ni Joṣua pa ìran àwọn Anakimu run patapata ní gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí òkè, àwọn ìlú bíi: Heburoni, Debiri, Anabu, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Juda, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Israẹli, gbogbo wọn patapata ni Joṣua parun, ati gbogbo ìlú wọn.

22 Àwọn ìran Anakimu yìí kò kù sí ibikíbi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, àfi ní ìlú Gasa, ìlú Gati, ati ìlú Aṣidodu ni àwọn díẹ̀ kù sí.

23 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose, ó sì pín in fún àwọn ọmọ Israẹli; ní ẹlẹ́yà-mẹ̀yà.Lẹ́yìn náà, wọ́n sinmi ogun jíjà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24