Joṣua 18 BM

Pípín Ilẹ̀ Yòókù

1 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun ilẹ̀ náà, gbogbo wọn péjọ sí Ṣilo, wọ́n sì pa àgọ́ àjọ níbẹ̀.

2 Ó ku ẹ̀yà meje, ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọn kò tíì pín ilẹ̀ fún.

3 Joṣua bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ìgbà wo ni ẹ fẹ́ dúró dà kí ẹ tó lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fun yín.

4 Ẹ yan eniyan mẹta mẹta wá láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì rán wọn jáde lọ láti rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí wọ́n lè ṣe àkọsílẹ̀ ibi tí wọ́n bá fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn, lẹ́yìn náà, kí wọ́n pada wá jíyìn fún mi.

5 Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá.

6 Ẹ óo ṣe àkọsílẹ̀ ìpín mejeeje, ẹ óo sì mú un tọ̀ mí wá. N óo ba yín ṣẹ́ gègé lórí wọn níhìn-ín, níwájú OLUWA Ọlọrun wa.

7 Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ba yín pín ilẹ̀ nítorí iṣẹ́ alufaa OLUWA ni ìpín tiwọn. Ẹ̀yà Gadi ati ti Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ìpín tiwọn tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani.”

8 Àwọn ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, Joṣua sì kìlọ̀ fún wọn, pé, “Ẹ rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sílẹ̀ wá fún mi. N óo sì ba yín ṣẹ́ gègé níhìn-ín níwájú OLUWA ní Ṣilo.” Àwọn ọkunrin náà bá lọ,

9 wọ́n rin ilẹ̀ náà jákèjádò, wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ àpèjúwe àwọn ìlú tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ní ìsọ̀rí meje sinu ìwé kan, wọ́n pada wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ninu àgọ́ ní Ṣilo.

10 Joṣua bá bá wọn ṣẹ́ gègé ní Ṣilo, níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe pín ilẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní ìpín tirẹ̀.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Bẹnjamini

11 Ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn wà ní ààrin ilẹ̀ ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Josẹfu.

12 Ní apá ìhà àríwá, ààlà ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ ní etí odò Jọdani, lọ sí ara òkè ní ìhà àríwá Jẹriko. Ó gba ààrin àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì pin sí aṣálẹ̀ Betafeni.

13 Láti ibẹ̀ ààlà ilẹ̀ náà gba apá ìhà gúsù, ní ọ̀nà Lusi, kọjá lọ sí ara òkè, (Lusi ni wọ́n ń pè ní Bẹtẹli tẹ́lẹ̀) ààlà náà tún yípo lọ sí apá ìsàlẹ̀, sí ọ̀nà Atarotu Adari, sí orí òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù, ni ìsàlẹ̀ Beti Horoni.

14 Ó tún yípo lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, sí apá ìhà gúsù lọ sí ara àwọn òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù tí ó dojú kọ Beti Horoni, ó sì pin sí Kiriati Baali (tí wọ́n tún ń pè ní Kiriati Jearimu), ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Juda. Èyí ni apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ náà.

15 Ààlà ti apá ìhà gúsù ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní àtiwọ ìlú Kiriati Jearimu lọ títí dé Efuroni, títí dé odò Nefitoa,

16 kí ó tó yípo lọ sí ìsàlẹ̀, sí ẹsẹ̀ òkè tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, níbi tí àfonífojì Refaimu pin sí ní ìhà àríwá. Ààlà náà la àfonífojì Hinomu kọjá lọ sí apá ìhà gúsù ní etí Jebusi, ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Enrogeli.

17 Lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí apá àríwá, kí ó tó wa lọ sí Enṣemeṣi títí lọ dé Gelilotu tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, lẹ́yìn náà ó wá sí ìsàlẹ̀ ní ibi tí òkúta Bohani ọmọ Reubẹni wà.

18 Ààlà náà kọjá lọ sí apá ìhà àríwá òkè Betaraba; láti ibẹ̀ ó lọ sí Araba.

19 Ó tún lọ sí apá ìhà àríwá òkè Beti Hogila, kí ó tó wá lọ sí apá etí Òkun Iyọ̀, níbi tí ó ti lọ fi orí sọ òpin odò Jọdani, ní ìhà gúsù. Ó jẹ́ ààlà ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini ní apá ìhà gúsù.

20 Odò Jọdani ni ààlà rẹ̀ ní apá ìlà oòrùn. Èyí ni ilẹ̀ tí a pín fún ẹ̀yà Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé, pẹlu àwọn ààlà ilẹ̀ ìdílé kọ̀ọ̀kan.

21 Àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni: Jẹriko, Beti Hogila, Emeki Kesisi;

22 Betaraba, Semaraimu, Bẹtẹli;

23 Afimu, Para, Ofira;

24 Kefariamoni, Ofini, ati Geba; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila.

25 Gibeoni, Rama, Beeroti

26 Misipa, Kefira, Mosa;

27 Rekemu, Iripeeli, Tarala;

28 Sela, Haelefi, Jebusi (tí à ń pè ní Jerusalẹmu) Gibea, ati Kiriati Jearimu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrinla. Ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24