Joṣua 16 BM

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1 Ààlà ilẹ̀ tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Josẹfu bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani lẹ́bàá Jẹriko, ní apá ìlà oòrùn àwọn odò Jẹriko, ó lọ títí dé apá aṣálẹ̀. Ó tún bẹ̀rẹ̀ láti Jẹriko lọ sí apá àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, títí dé Bẹtẹli.

2 Láti Bẹtẹli, ó lọ sí Lusi, ó sì kọjá lọ sí Atarotu, níbi tí àwọn ọmọ Ariki ń gbé.

3 Bákan náà ni ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn títí dé agbègbè àwọn ará Jafileti, títí dé apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni. Ó tún lọ láti ibẹ̀ títí dé Geseri, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.

4 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Josẹfu, tí à ń pè ní ẹ̀yà Manase ati ẹ̀yà Efuraimu ṣe gba ìpín tiwọn.

Efuraimu

5 Èyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Efuraimu gbà, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ààlà ilẹ̀ wọn ní apá ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ láti Atarotu Adari, títí dé apá òkè Beti Horoni.

6 Láti ibẹ̀ ó lọ títí dé Òkun Mẹditarenia. Mikimetati ni ààlà wọn ní ìhà àríwá. Ní apá ìlà oòrùn ibẹ̀, ààlà ilẹ̀ wọn yípo lọ sí apá Taanati Ṣilo, ó sì kọjá ibẹ̀ lọ ní ìhà ìlà oòrùn lọ sí Janoa.

7 Lẹ́yìn náà, ní ìsàlẹ̀, láti Janoa, lọ sí Atarotu ati Naara. Ó lọ títí dé Jẹriko, ó sì pin sí odò Jọdani.

8 Láti Tapua, ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé odò Kana, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Èyí ni ilẹ̀ tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Efuraimu gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,

9 pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọn tí ó wà ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Manase, ṣugbọn tí a fi fún ẹ̀yà Efuraimu.

10 Ṣugbọn wọn kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Geseri jáde, nítorí náà, àwọn ará Kenaani ń gbé ààrin ẹ̀yà Efuraimu títí di òní olónìí. Ẹ̀yà Efuraimu ń fi tipátipá mú wọn ṣiṣẹ́ bí ẹrú.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24