Joṣua 17 BM

Ilẹ̀ Ẹ̀yà Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1 Wọ́n pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Manase nítorí pé ó jẹ́ àkọ́bí Josẹfu. Makiri, baba Gileadi, tí ó jẹ́ àkọ́bí Manase ni wọ́n fún ní ilẹ̀ Gileadi ati Baṣani nítorí pé ó jẹ́ akọni ati akikanju eniyan.

2 Wọ́n fún àwọn ìdílé Manase yòókù ní ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn: àwọn bíi Abieseri, Heleki, Asirieli, Ṣekemu, Heferi, ati Ṣemida. Àwọn ni ọmọkunrin Manase, tíí ṣe ọmọ Josẹfu; wọ́n sì jẹ́ olórí fún àwọn ìdílé wọn.

3 Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkunrin rárá, àfi kìkì ọmọbinrin. Orúkọ wọn ni Mahila, Noa, Hogila, Milika, ati Tirisa.

4 Wọ́n tọ Eleasari, alufaa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn àgbààgbà lọ, wọ́n wí fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí ó pín ilẹ̀ fún àwa náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti pín fún àwọn ìbátan wa, tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.” Nítorí náà bí OLUWA ti pa á láṣẹ, wọ́n pín ilẹ̀ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pín fún àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.

5 Ìdí nìyí tí ìpín mẹ́wàá fi kan Manase láìka Gileadi, ati Baṣani ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani.

6 Nítorí pé àwọn ọmọbinrin Manase gba ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin. Wọ́n pín ilẹ̀ Gileadi fún àwọn ọmọ Manase yòókù.

7 Ilẹ̀ ti Manase bẹ̀rẹ̀ láti Aṣeri títí dé Mikimetati tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Ṣekemu, ààlà rẹ̀ tún lọ sí apá ìhà gúsù ní apá ọ̀dọ̀ àwọn tí wọn ń gbé Entapua.

8 Àwọn ọmọ Manase ni wọ́n ni ilẹ̀ Tapua, ṣugbọn ìlú Tapua gan-an, tí ó wà ní ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu.

9 Ààlà ilẹ̀ wọn tún lọ sí apá ìsàlẹ̀ títí dé odò Kana, àwọn ìlú wọnyi tí wọ́n wà ní apá gúsù odò náà, láàrin ìlú àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu. Ààlà àwọn ọmọ Manase tún lọ sí apá àríwá odò náà, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.

10 Ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìhà gúsù jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu, èyí tí ó wà ní apá ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn ọmọ Manase. Òkun Mẹditarenia ni ààlà wọn ní apá ìwọ̀ oòrùn. Ní apá ìhà àríwá, ilẹ̀ wọn lọ títí kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, ó sì kan ti ẹ̀yà Isakari ní apá ìlà oòrùn.

11 Ní ilẹ̀ Isakari, ati ti Aṣeri, àwọn ọmọ Manase ni wọ́n ni ìlú Beti Ṣeani ati àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀, Ibileamu ati àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀, ati Dori, Endori, Taanaki ati Megido ati gbogbo àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè wọn. Àwọn náà ni wọ́n ni Nafati.

12 Ṣugbọn àwọn ọmọ Manase kò lè gba àwọn ìlú náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ilẹ̀ náà.

13 Ṣugbọn nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi tipátipá mú àwọn ará Kenaani sìn, wọn kò sì lé wọn jáde patapata.

Ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase ti Ìwọ̀ Oòrùn Bèèrè fún Ilẹ̀ Sí i

14 Àwọn ẹ̀yà Josẹfu lọ bá Joṣua, wọ́n wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi fún wa ní ẹyọ ilẹ̀ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwa, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn eniyan wa pọ̀ gan-an, nítorí pé OLUWA ti bukun wa?”

15 Joṣua dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá pọ̀, ẹ lọ sí inú igbó, kí ẹ sì gba ilẹ̀ níbẹ̀ ninu ilẹ̀ àwọn ará Perisi ati ti àwọn Refaimu, bí ilẹ̀ olókè ti Efuraimu kò bá tóbi tó fun yín.”

16 Àwọn ẹ̀yà Josẹfu bá dáhùn pé, “Ilẹ̀ olókè yìí kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Kenaani tí ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn tí wọn ń gbé Beti Ṣani, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, ati àwọn tí ń gbé àfonífojì Jesireeli.”

17 Joṣua bá dá àwọn ọmọ Josẹfu: ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase lóhùn, ó ní, “Ẹ pọ̀ nítòótọ́, ẹ sì ní agbára, ilẹ̀ kan ṣoṣo kọ́ ni yóo kàn yín,

18 ẹ̀yin ni ẹ óo ni agbègbè olókè wọnyi pẹlu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó ni, ẹ gbà á, kí ẹ sì ṣán an láti òkè dé ilẹ̀ títí dé òpin ààlà rẹ̀. Ẹ óo lé àwọn ará Kenaani jáde, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irin ni wọ́n fi ṣe kẹ̀kẹ́ ogun wọn, tí wọ́n sì jẹ́ alágbára.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24