Joṣua 13 BM

Ilẹ̀ Tí Ó kù láti Gbà

1 Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà.

2 Ilẹ̀ tí ó kù nìwọ̀nyí: gbogbo agbègbè àwọn ará Filistia ati ti Geṣuri;

3 láti odò Ṣihori, ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ijipti, títí lọ sí apá àríwá ní ààlà Ekironi tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kenaani, (Marun-un ni ọba àwọn ará Filistia, àwọn nìwọ̀nyí: ọba Gasa, ti Aṣidodu, ti Aṣikeloni, ti Gati, ati ti Ekironi) ati ilẹ̀ àwọn Afimu ní ìhà gúsù.

4 Lẹ́yìn náà, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Meara, tíí ṣe ilẹ̀ àwọn ará Sidoni, títí dé Afeki ní ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amori,

5 ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati.

6 Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín.

7 Ẹ pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an yòókù ati ìdajì ẹ̀yà Manase.”

Pípín Agbègbè Tí Ó Wà ní Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

8 Ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase gba ilẹ̀ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani;

9 láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba títí dé Diboni;

10 ati gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, títí kan ààlà àwọn ará Amoni;

11 ati Gileadi ati agbègbè Geṣuri ti Maakati, ati gbogbo òkè Herimoni ati gbogbo Baṣani títí dé Saleka;

12 gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ti Baṣani, tí ó jọba ní Aṣitarotu ati Edirei. Ogu yìí nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́kù ninu ìran Refaimu yòókù. Mose ti ṣẹgun gbogbo wọn, ó sì ti lé wọn jáde.

13 Sibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri ati àwọn ará Maakati jáde; wọ́n ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní olónìí.

14 Ẹ̀yà Lefi nìkan ni Mose kò pín ilẹ̀ fún, ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí OLUWA ni ìpín tiwọn. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Reubẹni

15 Mose fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni ní ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

16 Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati gbogbo ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba.

17 Pẹlu Heṣiboni ati àwọn ìlú agbègbè rẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Àwọn ìlú bíi Diboni, Bamoti Baali, ati Beti Baalimeoni;

18 Jahasi, Kedemotu, ati Mefaati;

19 Kiriataimu, Sibima, ati Sereti Ṣahari, tí ó wà ní orí òkè àfonífojì náà;

20 Betipeori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga, ati Beti Jeṣimotu;

21 àní, àwọn ìlú tí ó wà ní orí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ati gbogbo ìjọba Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, tí Mose ṣẹgun, pẹlu gbogbo àwọn olórí ilẹ̀ Midiani. Àwọn bíi: Efi, Rekemu, Ṣuri, Huru, ati Reba, ọmọ ọba Sihoni, tí ń gbé ilẹ̀ náà.

22 Ọ̀kan ninu àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lójú ogun ni Balaamu, aláfọ̀ṣẹ, ọmọ Beori.

23 Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni. Àwọn ìlú ńláńlá ati àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ẹ̀yà Reubẹni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Gadi

24 Mose fún ẹ̀yà Gadi ní ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

25 Ilẹ̀ tiwọn ni Jaseri ati gbogbo ìlú Gileadi, ati ìdajì ilẹ̀ àwọn ará Amoni, títí dé Aroeri tí ó wà ní ìlà oòrùn Raba;

26 láti Heṣiboni, títí dé Ramati Misipe ati Betonimu; ati láti Mahanaimu títí dé agbègbè Debiri;

27 àfonífojì Beti Nimra, Sukotu, ati Safoni, ìyókù ilẹ̀ ìjọba Sihoni, ọba Heṣiboni. Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ wọn, ní apá ìsàlẹ̀ òkun Kinereti, lọ sí apá ìlà oòrùn, níkọjá odò Jọdani.

28 Àwọn ìlú ńláńlá ati ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ yìí jẹ́ ìpín ẹ̀yà Gadi gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Manase ní ìlà Oòrùn

29 Mose fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ìpín tiwọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

30 Ilẹ̀ tiwọn bẹ̀rẹ̀ láti Mahanaimu, títí dé gbogbo ilẹ̀ Baṣani, gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo àwọn ìlú Jairi tí ó wà ní Baṣani, gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta.

31 Ninu ilẹ̀ wọn ni ìdajì Gileadi wà ati Aṣitarotu ati Edirei, àwọn ìlú ńláńlá ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani; Mose pín wọn fún àwọn ìdajì ìdílé Makiri, ọmọ Manase, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

32 Àkọsílẹ̀ bí Mose ṣe pín ilẹ̀ tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani ní apá ìlà oòrùn Jẹriko nìyí.

33 Ṣugbọn Mose kò pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà Lefi, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24