Joṣua 22 BM

Joṣua Dá Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn Pada Sílé

1 Lẹ́yìn náà, Joṣua pe àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase,

2 ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ohun tí Mose, iranṣẹ OLUWA pa láṣẹ fun yín ni ẹ ti ṣe; ẹ sì ti ṣe gbogbo ohun tí èmi náà pa láṣẹ fun yín.

3 Ẹ kò kọ àwọn arakunrin yín sílẹ̀ láti ọjọ́ yìí wá títí di òní, ṣugbọn ẹ fara balẹ̀, ẹ sì ti ń pa gbogbo àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín mọ́.

4 Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn; nítorí náà, ẹ pada lọ sí ilẹ̀ yín, níbi tí ohun ìní yín wà, àní ilẹ̀ tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín ní òdìkejì odò Jọdani.

5 Ẹ máa ranti lemọ́lemọ́ láti máa pa gbogbo òfin tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín mọ́, pé kí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, ẹ máa pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ súnmọ́ ọn, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn.”

6 Joṣua bá súre fún wọn, lẹ́yìn náà, ó ní kí wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì pada lọ.

7 Mose ti kọ́kọ́ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ ní Baṣani; Joṣua sì fún ìdajì yòókù ní ilẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ti àwọn arakunrin wọn, ní ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani. Nígbà tí Joṣua rán wọn pada lọ sí ilé wọn, tí ó sì súre fún wọn, ó wí fún wọn pé,

8 “Ẹ máa kó ọpọlọpọ dúkìá pada lọ sí ilé yín, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn, fadaka, wúrà, idẹ, irin, ati ọpọlọpọ aṣọ. Ẹ pín ninu ìkógun tí ẹ kó lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá yín fún àwọn arakunrin yín.”

9 Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ọmọ Israẹli yòókù sílẹ̀ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì pada lọ sí ilẹ̀ Gileadi tí í ṣe ilẹ̀ tiwọn tí wọ́n pín fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.

Pẹpẹ Tí Ó Wà Lẹ́bàá Odò Jọdani

10 Nígbà tí wọ́n dé agbègbè odò Jọdani, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase tẹ́ pẹpẹ kan lẹ́bàá Jọdani, pẹpẹ náà tóbi pupọ.

11 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti tẹ́ pẹpẹ kan sí ìhà ibi tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, ní agbègbè odò Jọdani, ní àtiwọ ilẹ̀ Kenaani,

12 Nigba tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, gbogbo wọ́n bá péjọ sí Ṣilo láti lọ bá wọn jagun.

13 Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ sí ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ Gileadi, àwọn tí wọ́n rán ni Finehasi, ọmọ Eleasari, alufaa,

14 ati àwọn olórí mẹ́wàá; wọ́n yan olórí kọ̀ọ̀kan láti inú ìdílé Israẹli kọ̀ọ̀kan, olukuluku wọn sì jẹ́ baálé ninu ìdílé wọn.

15 Wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ Gileadi, wọ́n sọ fún wọn pé,

16 “Gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun ní kí á bèèrè lọ́wọ́ yín pé, irú ìwà ọ̀dàlẹ̀ wo ni ẹ hù sí OLUWA Ọlọrun Israẹli yìí? Ẹ ti yára pada lẹ́yìn OLUWA, ẹ kò sì tẹ̀lé e mọ́, nítorí pé ẹ ti ṣe oríkunkun sí OLUWA nípa títẹ́ pẹpẹ fún ara yín.

17 Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá ní Peori, tí a kò tíì wẹ ara wa mọ́ kúrò ninu rẹ̀ kò tíì tó? Ṣebí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ náà ni àjàkálẹ̀ àrùn fi bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin ìjọ eniyan OLUWA?

18 Kí ni ìbáà ṣẹlẹ̀, tí ẹ fi níláti yára yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ sì ni bí ẹ bá ṣe oríkunkun sí OLUWA lónìí, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni yóo bínú sí lọ́la.

19 Bí ó bá jẹ́ pé ilẹ̀ yín kò mọ́ tó láti máa sin OLUWA níbẹ̀ ni, ẹ rékọjá sinu ilẹ̀ OLUWA, níbi tí àgọ́ rẹ̀ wà, ẹ wá gba ilẹ̀ láàrin wa. Ẹ ṣá má ti ṣe oríkunkun sí OLUWA, tabi kí ẹ sọ gbogbo wa di olóríkunkun nípa títẹ́ pẹpẹ mìíràn, yàtọ̀ sí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa.

20 Ṣebí ìwà ọ̀dàlẹ̀ báyìí náà ni Akani ọmọ Sera hù nígbà tí ó kọ̀, tí kò tẹ̀lé àṣẹ tí OLUWA pa nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ OLUWA, ṣebí gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli ni OLUWA bínú sí? Àbí òun nìkan ni ó ṣègbé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?”

21 Ni àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase bá dá àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli lóhùn pé,

22 “Ọlọrun Alágbára, Ọlọrun ni OLUWA! Ọlọrun Alágbára, Ọlọrun ni OLUWA, ó mọ ìdí tí a fi ṣe ohun tí a ṣe, a sì fẹ́ kí ẹ̀yin ọmọ Israẹli náà mọ̀ pẹlu. Tí ó bá jẹ́ pé oríkunkun ati ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni a fẹ́ hù sí OLUWA ni a fi ṣe ohun tí a ṣe, ẹ má ṣàánú wa.

23 Bí ó bá jẹ́ pé a tẹ́ pẹpẹ tí yóo mú wa kọ OLUWA sílẹ̀, tabi pé a tẹ́ pẹpẹ fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ alaafia, kí OLUWA gbẹ̀san lára wa.

24 Ká má rí i! Ohun tí ó mú wa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ẹ̀rù ń bà wá pé, nígbà tí ó bá di ọjọ́ iwájú, àwọn ọmọ yín lè wí fún àwọn ọmọ wa pé, ‘Ọ̀rọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli kò kàn yín.

25 Nítorí OLUWA ti fi odò Jọdani ṣe ààlà láàrin àwa pẹlu yín, ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’ Àwọn ọmọ yín sì lè mú kí àwọn ọmọ wa má sin OLUWA mọ́.

26 Nítorí náà, ni a ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á tẹ́ pẹpẹ kan,’ kì í ṣe fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ mìíràn,

27 ṣugbọn yóo wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, láàrin àwa pẹlu yín, ati àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn wa, pé àwa náà yóo máa sin OLUWA, a óo sì máa rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú rẹ̀. Kí àwọn ọmọ yín má baà wí fún àwọn ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’

28 Èyí ni a fi ronú pé, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀ sí wa, tabi sí àwọn ọmọ ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú, a óo lè wí pé, ẹ wo irú pẹpẹ OLUWA tí àwọn baba ńlá wá tẹ́, kì í ṣe pé wọ́n rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀, tabi ẹbọ mìíràn. Ẹ̀rí ni wọ́n fi ṣe láàrin àwa pẹlu yín.

29 A kò jẹ́ ṣe oríkunkun sí OLUWA tabi kí á kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kí a má sì sìn ín mọ́ kí á wá tẹ́ pẹpẹ mìíràn fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia tabi ẹbọ mìíràn, yàtọ̀ sí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa tí ó wà níwájú àgọ́ rẹ̀.”

30 Nígbà tí Finehasi alufaa, ati àwọn olórí ìjọ eniyan, ati àwọn olórí ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu wọn, gbọ́ ohun tí àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase wí, ọ̀rọ̀ náà dùn mọ́ wọn ninu.

31 Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa dá wọn lóhùn, ó ní, “Lónìí a mọ̀ pé OLUWA ń bẹ ní ààrin wa, nítorí pé ẹ kò hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí OLUWA, ẹ sì ti gba eniyan Israẹli lọ́wọ́ ìjìyà OLUWA.”

32 Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa, ati àwọn olórí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ní ilẹ̀ Gileadi; wọ́n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì jíṣẹ́ fún wọn.

33 Iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ náà dùn mọ́ àwọn ọmọ Israẹli ninu, wọ́n sì fi ìyìn fún Ọlọrun; wọn kò sì ronú ati bá wọn jagun mọ́, tabi àtipa ilẹ̀ wọn run níbi tí wọ́n ń gbé.

34 Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi bá pe pẹpẹ tí wọ́n tẹ́ ní, “Ẹ̀rí” nítorí wọ́n ní, “Pẹpẹ náà ni ẹ̀rí láàrin wa pé, OLUWA ni Ọlọrun.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24