1 Àpèjúwe ìpín tí ó kan ẹ̀yà Juda lára ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà, tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn nìyí:Ilẹ̀ náà lọ títí dé apá ìhà gúsù, ní ààlà ilẹ̀ Edomu, títí dé aṣálẹ̀ Sini.
2 Ààlà ilẹ̀ wọn, ní ìhà gúsù lọ láti òpin Òkun Iyọ̀,
3 láti apá etí òkun tí ó kọjú sí ìhà gúsù lọ títí dé àtigun òkè Akirabimu. Ó lọ títí dé Sini, ó tún lọ sí apá gúsù Kadeṣi Banea. Ó kọjá lọ lẹ́bàá Hesironi títí dé Adari, kí ó tó wá yípo lọ sí ìhà Kaka.
4 Lẹ́yìn náà, ó lọ títí dé Asimoni, ó tọ ipa odò Ijipti, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Òun ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ Juda ní apá ìhà gúsù.