1 Àpèjúwe ìpín tí ó kan ẹ̀yà Juda lára ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà, tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn nìyí:Ilẹ̀ náà lọ títí dé apá ìhà gúsù, ní ààlà ilẹ̀ Edomu, títí dé aṣálẹ̀ Sini.
2 Ààlà ilẹ̀ wọn, ní ìhà gúsù lọ láti òpin Òkun Iyọ̀,
3 láti apá etí òkun tí ó kọjú sí ìhà gúsù lọ títí dé àtigun òkè Akirabimu. Ó lọ títí dé Sini, ó tún lọ sí apá gúsù Kadeṣi Banea. Ó kọjá lọ lẹ́bàá Hesironi títí dé Adari, kí ó tó wá yípo lọ sí ìhà Kaka.
4 Lẹ́yìn náà, ó lọ títí dé Asimoni, ó tọ ipa odò Ijipti, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Òun ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ Juda ní apá ìhà gúsù.
5 Òkun Iyọ̀ ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn, ó lọ títí dé ibi tí odò Jọdani ti ń ṣàn wọ inú òkun.Níbẹ̀ ni ààlà rẹ̀ ní apá àríwá ti bẹ̀rẹ̀,
6 ó lọ títí dé Beti Hogila, ó lọ dé ìhà àríwá Betaraba, ó tún lọ títí dé ibi òkúta Bohani ọmọ Reubẹni.
7 Ó lọ láti àfonífojì Akori títí dé Debiri, ó wá yípo lọ sí apá ìhà àríwá, lọ sí Giligali, tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, tí ó wà ní apá gúsù àfonífojì náà. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ibi odò Enṣemeṣi, ó sì pin sí Enrogeli.